الصافات
As-Saaffaat
Translation: Yoruba - Abu Rahima Mikhail Aikweiny · Open the surah
بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
وَٱلصَّٰٓفَّٰتِ صَفّٗا
Open ayah 37:1Allāhu fi àwọn mọlāika tí ó ń tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ búra.
فَٱلزَّٰجِرَٰتِ زَجۡرٗا
Open ayah 37:2Allāhu tún fi àwọn mọlāika tó ń wọ́ ẹ̀ṣújò kiri tààrà bura.
فَٱلتَّٰلِيَٰتِ ذِكۡرًا
Open ayah 37:3Allāhu tún fi àwọn mọlāika tó ń ka ìrántí bura.
إِنَّ إِلَٰهَكُمۡ لَوَٰحِدٞ
Open ayah 37:4Dájúdájú ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo.
رَّبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا وَرَبُّ ٱلۡمَشَٰرِقِ
Open ayah 37:5Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Òun sì ni Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn.
إِنَّا زَيَّنَّا ٱلسَّمَآءَ ٱلدُّنۡيَا بِزِينَةٍ ٱلۡكَوَاكِبِ
Open ayah 37:6Dájúdájú Àwa fi àwọn ìràwọ̀ ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́
وَحِفۡظٗا مِّن كُلِّ شَيۡطَٰنٖ مَّارِدٖ
Open ayah 37:7àti ìṣọ́ kúrò níbi (aburú) gbogbo èṣù olóríkunkun.
لَّا يَسَّمَّعُونَ إِلَى ٱلۡمَلَإِ ٱلۡأَعۡلَىٰ وَيُقۡذَفُونَ مِن كُلِّ جَانِبٖ
Open ayah 37:8(Àwọn èṣù) kò sì níí lè tẹ́tí sí ìjọ (mọlāika tó wà ní) àyè gíga jùlọ (nínú sánmọ̀. Bí wọ́n bá sì gbìyànjú láti yọ́ ọ̀rọ̀ gbọ́ láti sánmọ̀, àwọn mọlāika) yó sì máa kù wọ́n lókò (ẹ̀ta ìràwọ̀) ní gbogbo agbègbè (sánmọ̀).
دُحُورٗاۖ وَلَهُمۡ عَذَابٞ وَاصِبٌ
Open ayah 37:9Wọ́n máa lé wọn dànù. Ìyà àìlópin sì wà fún wọn.
إِلَّا مَنۡ خَطِفَ ٱلۡخَطۡفَةَ فَأَتۡبَعَهُۥ شِهَابٞ ثَاقِبٞ
Open ayah 37:10(Wọn kò níí gbọ́ ọ̀rọ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́) àyàfi ẹni tí ó bá rí ọ̀rọ̀ àjígbọ́ gbé, nígbà náà (ni mọlāika) yó sì fi ẹ̀ta ìràwọ̀ iná tó máa jó o tẹ̀lé e.[1]
- Àwọn èṣù àlùjànnú máa ń gbé ara wọn gunra wọn láti lè súnmọ́ etí sánmọ̀ ilé ayé. Bí wọ́n bá bá àwọn mọlāika lórí àwọn ìro kan tí Allāhu fi ránṣẹ́ sí wọn, wọ́n máa jí i gbọ́. Níkété tí àwọn mọlāika bá fura sí wọn, wọ́n máa fi adó olóró ẹta ìràwọ̀ tú wọn ká. Nígbà mìíràn, àwọn èṣù àlùjànnú yìí yóò ti ṣe àtagbà ìró náà síra wọn tán ṣíwájú kí wọ́n tó tú wọn ká. Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ẹni tí ó wà lókè pátápátá nínú wọn, kò níí tí ì ṣe àtagbà ìró sí àwọn yòókù rẹ̀ ṣíwájú kí wọ́n tó tú wọn ká. Èyí tí wọ́n bá jàjà rí jí gbé lọ, wọ́n máa lọ kọ bí àkùkọ sínú etí àwọn ẹni wọn nínú àwọn èṣù ènìyàn tí wọ́n yẹsẹ́ wò. Wọ́n sì máa fi irọ́ ọgọ́rùn-ún kún un fúnra wọn ní ọ̀dọ̀ àwọn tó ń pawọ́ dà, tí wọ́n ń yẹsẹ́ wò.
فَٱسۡتَفۡتِهِمۡ أَهُمۡ أَشَدُّ خَلۡقًا أَم مَّنۡ خَلَقۡنَآۚ إِنَّا خَلَقۡنَٰهُم مِّن طِينٖ لَّازِبِۭ
Open ayah 37:11Bi wọ́n léèrè wò pé, ṣé àwọn (ènìyàn) ni ìṣẹ̀dá wọn lágbára jùlọ ni tàbí àwọn (n̄ǹkan mìíràn)[1] tí A dá? Dájúdájú Àwa dá àwọn (ènìyàn) láti ara ẹrẹ̀ tó lẹ̀ mọ́ra wọn.
- Àwọn n̄ǹkan mìíràn bíi àwọn sánmọ̀, àwọn ilẹ̀, àwọn mọlāika àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
بَلۡ عَجِبۡتَ وَيَسۡخَرُونَ
Open ayah 37:12Rárá (kò jọra wọn); ìwọ ṣèèmọ̀ (nípa al-Ƙur’ān), àwọn sì ń ṣe yẹ̀yẹ́.
وَإِذَا ذُكِّرُواْ لَا يَذۡكُرُونَ
Open ayah 37:13Àti pé nígbà tí wọ́n bá ṣe ìrántí fún wọn, wọn kò níí lo ìrántí.
وَإِذَا رَأَوۡاْ ءَايَةٗ يَسۡتَسۡخِرُونَ
Open ayah 37:14Nígbà tí wọ́n bá tún rí àmì kan, wọn yóò máa ṣe yẹ̀yẹ́.
وَقَالُوٓاْ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٞ مُّبِينٌ
Open ayah 37:15Wọ́n sì wí pé: “Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.
أَءِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابٗا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَبۡعُوثُونَ
Open ayah 37:16Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò tún gbé wa dìde ni?
أَوَءَابَآؤُنَا ٱلۡأَوَّلُونَ
Open ayah 37:17Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?”
قُلۡ نَعَمۡ وَأَنتُمۡ دَٰخِرُونَ
Open ayah 37:18Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀yin yó sì di ẹni yẹpẹrẹ.”
فَإِنَّمَا هِيَ زَجۡرَةٞ وَٰحِدَةٞ فَإِذَا هُمۡ يَنظُرُونَ
Open ayah 37:19Nítorí náà, igbe ẹyọ kan mà ni. Nígbà náà ni wọn yóò máa wò sùn.
وَقَالُواْ يَٰوَيۡلَنَا هَٰذَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ
Open ayah 37:20Wọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò! Èyí ni Ọjọ́ ẹ̀san.”
هَٰذَا يَوۡمُ ٱلۡفَصۡلِ ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ
Open ayah 37:21Èyí ni ọjọ́ Ìdájọ́ èyí tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.
۞ٱحۡشُرُواْ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ وَأَزۡوَٰجَهُمۡ وَمَا كَانُواْ يَعۡبُدُونَ
Open ayah 37:22Ẹ kó àwọn tó ṣàbòsí jọ, àwọn ìyàwó wọn àti ohun tí wọ́n ń jọ́sìn fún
مِن دُونِ ٱللَّهِ فَٱهۡدُوهُمۡ إِلَىٰ صِرَٰطِ ٱلۡجَحِيمِ
Open ayah 37:23lẹ́yìn Allāhu. Kí ẹ sì júwe wọn sí ojú ọ̀nà iná Jẹhīm.
وَقِفُوهُمۡۖ إِنَّهُم مَّسۡـُٔولُونَ
Open ayah 37:24Ẹ dá wọn dúró ná, dájúdájú wọ́n máa bi wọ́n léèrè ìbéèrè.
مَا لَكُمۡ لَا تَنَاصَرُونَ
Open ayah 37:25Kí ni kò jẹ́ kí ẹ ran ara yín lọ́wọ́?
بَلۡ هُمُ ٱلۡيَوۡمَ مُسۡتَسۡلِمُونَ
Open ayah 37:26Rárá, wọ́n ti juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ ní òní ni.
وَأَقۡبَلَ بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ يَتَسَآءَلُونَ
Open ayah 37:27Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bi ara wọn léèrè ìbéèrè.[1]
- Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mu’minūn; 23:101.
قَالُوٓاْ إِنَّكُمۡ كُنتُمۡ تَأۡتُونَنَا عَنِ ٱلۡيَمِينِ
Open ayah 37:28(Àwọn ènìyàn) wí pé: “Dájúdájú ẹ̀yin l’ẹ̀ ń gba ọ̀tún wọlé sí wa lára (láti ṣì wá lọ́nà).”[1]
- Gbígba ọ̀tún wọlé sí ni lára ni pé, wọ́n ń lo orúkọ ’Islām láti fi pe àwọn ènìyàn lọ síbi ìṣẹbọ dípò mímú Allāhu ní Ọ̀kan ṣoṣo. Àpẹ̀ẹrẹ àwọn wọ̀nyí ni àwọn àáfà tí wọ́n bá àwọn àlùjọ̀nnú dòwò pọ̀ tán, tí wọ́n sọra wọn di oníṣẹ́-ìyanu àti àwọn onibidiah bí ìjọ Ahmadiyyah àti ìjọ Tijāniyyah.
قَالُواْ بَل لَّمۡ تَكُونُواْ مُؤۡمِنِينَ
Open ayah 37:29(Àwọn àlùjànnú) wí pé: “Rárá o (àwa kọ́), ẹ̀yin ni ẹ kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
وَمَا كَانَ لَنَا عَلَيۡكُم مِّن سُلۡطَٰنِۭۖ بَلۡ كُنتُمۡ قَوۡمٗا طَٰغِينَ
Open ayah 37:30Àti pé àwa kò ní agbára kan lórí yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ìjọ olùtayọ-ẹnu ààlà.
فَحَقَّ عَلَيۡنَا قَوۡلُ رَبِّنَآۖ إِنَّا لَذَآئِقُونَ
Open ayah 37:31Ọ̀rọ̀ Olúwa wa sì kò lé wa lórí pé dájúdájú àwa yóò tọ́ Iná wò.
فَأَغۡوَيۡنَٰكُمۡ إِنَّا كُنَّا غَٰوِينَ
Open ayah 37:32Nítorí náà, a ṣì yín lọ́nà. Dájúdájú àwa náà sì jẹ́ olùṣìnà.”
فَإِنَّهُمۡ يَوۡمَئِذٖ فِي ٱلۡعَذَابِ مُشۡتَرِكُونَ
Open ayah 37:33Dájúdájú ní ọjọ́ yẹn, akẹgbẹ́ ni wọ́n nínú Ìyà. (Wọ́n dìjọ máa wà nínú Iná.)
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَفۡعَلُ بِٱلۡمُجۡرِمِينَ
Open ayah 37:34Dájúdájú báyẹn ni Àwa yóò ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
إِنَّهُمۡ كَانُوٓاْ إِذَا قِيلَ لَهُمۡ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا ٱللَّهُ يَسۡتَكۡبِرُونَ
Open ayah 37:35Dájúdájú nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé “Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu.”, wọn yóò máa ṣègbéraga.
وَيَقُولُونَ أَئِنَّا لَتَارِكُوٓاْ ءَالِهَتِنَا لِشَاعِرٖ مَّجۡنُونِۭ
Open ayah 37:36Wọ́n sì ń wí pé: “Ṣé a máa fi àwọn òrìṣà wa sílẹ̀ nítorí eléwì wèrè kan?”
بَلۡ جَآءَ بِٱلۡحَقِّ وَصَدَّقَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Open ayah 37:37Kò rí bẹ́ẹ̀. Ó mú òdodo wá ni. Ó sì ń jẹ́rìí sí òdodo àwọn Òjíṣẹ́ náà.
إِنَّكُمۡ لَذَآئِقُواْ ٱلۡعَذَابِ ٱلۡأَلِيمِ
Open ayah 37:38Dájúdájú ẹ máa tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò.
وَمَا تُجۡزَوۡنَ إِلَّا مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
Open ayah 37:39A kò níí san yín ní ẹ̀san kan àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ
Open ayah 37:40Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).
أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ رِزۡقٞ مَّعۡلُومٞ
Open ayah 37:41Ti àwọn wọ̀nyẹn sì ni arísìkí tí wọ́n ti mọ̀;
فَوَٰكِهُ وَهُم مُّكۡرَمُونَ
Open ayah 37:42àwọn èso. Àwọn sì ni alápọ̀n-ọ́nlé
فِي جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ
Open ayah 37:43nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
عَلَىٰ سُرُرٖ مُّتَقَٰبِلِينَ
Open ayah 37:44Lórí àwọn ìtẹ́ ni wọn yóò ti kọjú síra wọn.
يُطَافُ عَلَيۡهِم بِكَأۡسٖ مِّن مَّعِينِۭ
Open ayah 37:45Wọn yóò máa gbé ife ọtí mímọ́ láti inú odò kan tó ń ṣàn káà kiri ọ̀dọ̀ wọn.
بَيۡضَآءَ لَذَّةٖ لِّلشَّٰرِبِينَ
Open ayah 37:46Funfun ni (ọtí náà). Ó ń dùn lẹ́nu àwọn tó máa mu ún.
لَا فِيهَا غَوۡلٞ وَلَا هُمۡ عَنۡهَا يُنزَفُونَ
Open ayah 37:47Kò sí ìpalára kan fún wọn nínú rẹ̀, wọn kò sì níí hunrírà lórí rẹ̀.
وَعِندَهُمۡ قَٰصِرَٰتُ ٱلطَّرۡفِ عِينٞ
Open ayah 37:48Àwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, àwọn ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ yó sì wà lọ́dọ̀ wọn.
كَأَنَّهُنَّ بَيۡضٞ مَّكۡنُونٞ
Open ayah 37:49Wọ́n dà bí ẹyin tí wọn kò ì bó èèpo rẹ̀ kúrò lára rẹ̀.[1]
- Àwọn nasọ̄rọ̄, nínú ọ̀rọ̀ wọn kan tí wọ́n ń fi tàbùkù àwọn ìkẹ́ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, wọ́n sọ pé, “Nítorí ọ̀wọ́n èso ní erúkùsù ilẹ̀ Lárúbáwá ni Allāhu fi ṣàdéhùn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso fún àwọn mùsùlùmí nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀; nítorí pé àwọn Lárúbáwá fẹ́ràn ọtí àmupara ni Allāhu fi bá wọn pèsè ọtí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sílẹ̀ dè wọ́n nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀; nítorí pé àwọn Lárúbáwá fẹ́ràn àgbèrè ṣíṣe ni Allāhu fi bá wọn pèsè obìnrin ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sílẹ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn mùsùlùmí nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀!” Èsì: Ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn nasọ̄rọ̄ wọ̀nyí, yàtọ̀ sí pé ó ń fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí aláwàdà kẹríkẹrì, ó tún jẹ́ kí á mọ̀ pé wọn kò retí ìkẹ́ kan kan lọ́run ní tiwọn. Tí ó bá jẹ́ pé, wọ́n ń retí ìkẹ́ kan ní ọ̀run, irú ìkẹ́ wo gan-an ni wọ́n ń retí nígbà náà? Síwájú sí i, kì í kúkú ṣe Lárúbáwá nìkan ni mùsùlùmí. Gbogbo àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu ni mùsùlùmí. Àwọn nasọ̄rọ̄ ṣe wá ń sọ̀rọ̀ bí ẹni pé nítorí Lárúbáwá nìkan ni Allāhu fi dá Ọgbà Ìdẹ̀ra! Ìgbádùn inú Ọgbà Ìdẹ̀ra wulẹ̀ pọ̀ tayọ èso, ọtí tí kì í pani àti obìnrin. Àmọ́ sá, kò wulẹ̀ sí ìgbádùn kan kan fún àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́run bí kò ṣe Iná gbére.
فَأَقۡبَلَ بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ يَتَسَآءَلُونَ
Open ayah 37:50Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè.
قَالَ قَآئِلٞ مِّنۡهُمۡ إِنِّي كَانَ لِي قَرِينٞ
Open ayah 37:51Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn yóò sọ pé: "Dájúdájú èmi ní ọ̀rẹ́ kan
يَقُولُ أَءِنَّكَ لَمِنَ ٱلۡمُصَدِّقِينَ
Open ayah 37:52tí ó ń wí pé, “Ṣé dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn onígbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Àjíǹde?
أَءِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابٗا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَدِينُونَ
Open ayah 37:53Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò san wá ní ẹ̀san ni?”
قَالَ هَلۡ أَنتُم مُّطَّلِعُونَ
Open ayah 37:54Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò yọjú wo (ẹni náà tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ àjíǹde)?”
فَٱطَّلَعَ فَرَءَاهُ فِي سَوَآءِ ٱلۡجَحِيمِ
Open ayah 37:55Ó yọjú wò ó. Ó sì rí i láààrin gbùngbùn nínú iná Jẹhīm.
قَالَ تَٱللَّهِ إِن كِدتَّ لَتُرۡدِينِ
Open ayah 37:56Ó (sì) sọ pé: “Mó fi Allāhu búra, ìwọ fẹ́ẹ̀ kó ìparun bá mi tán.
وَلَوۡلَا نِعۡمَةُ رَبِّي لَكُنتُ مِنَ ٱلۡمُحۡضَرِينَ
Open ayah 37:57Àti pé tí kì í bá ṣe ìdẹ̀ra Olúwa mi ni, èmi náà ìbá wà nínú ẹni tí wọ́n máa mú wá sínú Iná.
أَفَمَا نَحۡنُ بِمَيِّتِينَ
Open ayah 37:58Àwa kò sá níí kú mọ́ báyìí?
إِلَّا مَوۡتَتَنَا ٱلۡأُولَىٰ وَمَا نَحۡنُ بِمُعَذَّبِينَ
Open ayah 37:59Àfi ikú wa àkọ́kọ́. Wọn kò sì níí jẹ àwa níyà.
إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ
Open ayah 37:60Dájúdájú èyí, òhun ni èrèǹjẹ ńlá.”
لِمِثۡلِ هَٰذَا فَلۡيَعۡمَلِ ٱلۡعَٰمِلُونَ
Open ayah 37:61Nítorí irú èyí, kí àwọn olùṣẹ̀sìn máa ṣẹ̀sìn lọ.
أَذَٰلِكَ خَيۡرٞ نُّزُلًا أَمۡ شَجَرَةُ ٱلزَّقُّومِ
Open ayah 37:62Ǹjẹ́ ìyẹn l’ó lóore jùlọ ní ibùdésí ni tàbí igi zaƙūm (igi ẹlẹ́gùn-ún)?
إِنَّا جَعَلۡنَٰهَا فِتۡنَةٗ لِّلظَّٰلِمِينَ
Open ayah 37:63Dájúdájú Àwa ṣe é ní àdánwò fún àwọn alábòsí.
إِنَّهَا شَجَرَةٞ تَخۡرُجُ فِيٓ أَصۡلِ ٱلۡجَحِيمِ
Open ayah 37:64Dájúdájú òhun ni igi kan tí ó máa hù jáde láti ìdí iná Jẹhīm.
طَلۡعُهَا كَأَنَّهُۥ رُءُوسُ ٱلشَّيَٰطِينِ
Open ayah 37:65Èso rẹ̀ dà bí orí àwọn èṣù.
فَإِنَّهُمۡ لَأٓكِلُونَ مِنۡهَا فَمَالِـُٔونَ مِنۡهَا ٱلۡبُطُونَ
Open ayah 37:66Dájúdájú wọn yóò máa jẹ nínú rẹ̀. Wọ́n sì máa jẹ ẹ́ ní àjẹyo bámúbámú.
ثُمَّ إِنَّ لَهُمۡ عَلَيۡهَا لَشَوۡبٗا مِّنۡ حَمِيمٖ
Open ayah 37:67Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò mu àwọnúwẹ̀jẹ̀ olómi gbígbóná tó gbóná parí lé e lórí.
ثُمَّ إِنَّ مَرۡجِعَهُمۡ لَإِلَى ٱلۡجَحِيمِ
Open ayah 37:68Lẹ́yìn náà, dájúdájú ibùpadàsí wọn ni iná Jẹhīm.
إِنَّهُمۡ أَلۡفَوۡاْ ءَابَآءَهُمۡ ضَآلِّينَ
Open ayah 37:69Dájúdájú wọ́n bá àwọn bàbá wọn ní olùṣìnà.
فَهُمۡ عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِمۡ يُهۡرَعُونَ
Open ayah 37:70Àwọn náà sì ń yára tẹ̀lé orípa wọn.
وَلَقَدۡ ضَلَّ قَبۡلَهُمۡ أَكۡثَرُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Open ayah 37:71Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti ṣìnà ṣíwájú wọn.
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا فِيهِم مُّنذِرِينَ
Open ayah 37:72Dájúdájú A ti rán àwọn olùkìlọ̀ sí wọn.
فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُنذَرِينَ
Open ayah 37:73Nítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ti rí.
إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ
Open ayah 37:74Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).
وَلَقَدۡ نَادَىٰنَا نُوحٞ فَلَنِعۡمَ ٱلۡمُجِيبُونَ
Open ayah 37:75Dájúdájú (Ànábì) Nūh pè Wá. A sì dára ní olùjẹ́pè.
وَنَجَّيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥ مِنَ ٱلۡكَرۡبِ ٱلۡعَظِيمِ
Open ayah 37:76A gba òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá náà.
وَجَعَلۡنَا ذُرِّيَّتَهُۥ هُمُ ٱلۡبَاقِينَ
Open ayah 37:77A dá àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ sí lẹ́yìn rẹ̀.
وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ
Open ayah 37:78A sì fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
سَلَٰمٌ عَلَىٰ نُوحٖ فِي ٱلۡعَٰلَمِينَ
Open ayah 37:79Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Nūh láààrin gbogbo ẹ̀dá.
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Open ayah 37:80Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Open ayah 37:81Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
ثُمَّ أَغۡرَقۡنَا ٱلۡأٓخَرِينَ
Open ayah 37:82Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn yòókù rì sínú agbami.
۞وَإِنَّ مِن شِيعَتِهِۦ لَإِبۡرَٰهِيمَ
Open ayah 37:83Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm wà nínú ìjọ (tí ó tẹ̀lé ìlànà) rẹ̀.[1]
- Ìyẹn ni pé, ẹ̀sìn Ànábì Nūh ni ẹ̀sìn Ànábì ’Ibrọ̄hīm - aleehimọ sọlātu wa salām -, ẹ̀sìn ’Islām.
إِذۡ جَآءَ رَبَّهُۥ بِقَلۡبٖ سَلِيمٍ
Open ayah 37:84(Ẹ rántí) nígbà tí ó dojú kọ Olúwa rẹ̀ pẹ̀lú ọkàn mímọ́.
إِذۡ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوۡمِهِۦ مَاذَا تَعۡبُدُونَ
Open ayah 37:85(Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: "Kí ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún?
أَئِفۡكًا ءَالِهَةٗ دُونَ ٱللَّهِ تُرِيدُونَ
Open ayah 37:86Ṣé ẹ̀ ń gbèrò láti sọ irọ́ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu?
فَمَا ظَنُّكُم بِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Open ayah 37:87Kí sì ni èrò ọkàn yín sí Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”[1]
- Ìyẹn ni pé, ẹ̀san rere ni ẹ̀ ń retí ni tàbí ẹ̀san aburú?
فَنَظَرَ نَظۡرَةٗ فِي ٱلنُّجُومِ
Open ayah 37:88Ó ṣíjú wo àwọn ìràwọ̀ ní wíwò kan.
فَقَالَ إِنِّي سَقِيمٞ
Open ayah 37:89Ó sì sọ pé: “Dájúdájú ó rẹ̀ mí.”
فَتَوَلَّوۡاْ عَنۡهُ مُدۡبِرِينَ
Open ayah 37:90Nítorí náà, wọ́n pa á tì, wọ́n sì lọ.
فَرَاغَ إِلَىٰٓ ءَالِهَتِهِمۡ فَقَالَ أَلَا تَأۡكُلُونَ
Open ayah 37:91Nígbà náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òrìṣà wọn. Ó sì sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí jẹun ni?
مَا لَكُمۡ لَا تَنطِقُونَ
Open ayah 37:92Kí ni ó ṣe yín tí ẹ kò sọ̀rọ̀?”
فَرَاغَ عَلَيۡهِمۡ ضَرۡبَۢا بِٱلۡيَمِينِ
Open ayah 37:93Nígbà náà, ó dojú lílù kọ wọ́n pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún (ó sì rún wọn wómúwómú).
فَأَقۡبَلُوٓاْ إِلَيۡهِ يَزِفُّونَ
Open ayah 37:94(Àwọn abọ̀rìṣà) sáré wá dojú kọ ọ́.
قَالَ أَتَعۡبُدُونَ مَا تَنۡحِتُونَ
Open ayah 37:95Ó sọ pé: “Ṣé ẹ óò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí ẹ gbẹ́ kalẹ̀ lére ni?
وَٱللَّهُ خَلَقَكُمۡ وَمَا تَعۡمَلُونَ
Open ayah 37:96Allāhu l’Ó sì dá ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
قَالُواْ ٱبۡنُواْ لَهُۥ بُنۡيَٰنٗا فَأَلۡقُوهُ فِي ٱلۡجَحِيمِ
Open ayah 37:97Wọ́n wí pé: “Ẹ mọ ilé kan fún un, kí ẹ sì jù ú sínú iná.”
فَأَرَادُواْ بِهِۦ كَيۡدٗا فَجَعَلۡنَٰهُمُ ٱلۡأَسۡفَلِينَ
Open ayah 37:98Wọ́n gbèrò ète sí i. A sì sọ wọ́n di ẹni yẹpẹrẹ.
وَقَالَ إِنِّي ذَاهِبٌ إِلَىٰ رَبِّي سَيَهۡدِينِ
Open ayah 37:99Ó sọ pé: “Dájúdájú mo máa lọ sí (ìlú tí) Olúwa mi (pa mí láṣẹ láti lọ). Ó sì máa tọ́ mi sọ́nà (láti dé ibẹ̀).[1]
- Ìyẹn ìlú Ṣām.
رَبِّ هَبۡ لِي مِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ
Open ayah 37:100Olúwa mi, ta mí lọ́rẹ ọmọ nínú àwọn ẹni rere.”
فَبَشَّرۡنَٰهُ بِغُلَٰمٍ حَلِيمٖ
Open ayah 37:101A sì fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan tí ó máa ní ìfaradà.
فَلَمَّا بَلَغَ مَعَهُ ٱلسَّعۡيَ قَالَ يَٰبُنَيَّ إِنِّيٓ أَرَىٰ فِي ٱلۡمَنَامِ أَنِّيٓ أَذۡبَحُكَ فَٱنظُرۡ مَاذَا تَرَىٰۚ قَالَ يَٰٓأَبَتِ ٱفۡعَلۡ مَا تُؤۡمَرُۖ سَتَجِدُنِيٓ إِن شَآءَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلصَّٰبِرِينَ
Open ayah 37:102Nígbà tí (ọmọ náà) dàgbà, tí ó tó bá (bàbá rẹ̀) ṣe iṣẹ́, (bàbá rẹ̀) sọ pé: "Ọmọ mi, dájúdájú èmi lá àlá pé dájúdájú mò ń dúńbú rẹ. Nítorí náà, wòye sí i, kí ni o rí sí i." Ó sọ pé: “Bàbá mi, ṣe ohun tí Wọ́n pa láṣẹ fún ọ. O máa bá mi nínú àwọn onísùúrù, tí Allāhu bá fẹ́.”
فَلَمَّآ أَسۡلَمَا وَتَلَّهُۥ لِلۡجَبِينِ
Open ayah 37:103Nígbà tí àwọn méjèèjì juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀, tí (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sì dojú[1] (ọmọ) rẹ̀ bolẹ̀,
- Ìtúmọ̀ “jẹbīn” ni iwájú orí.
وَنَٰدَيۡنَٰهُ أَن يَٰٓإِبۡرَٰهِيمُ
Open ayah 37:104A pè é (báyìí) pé, ’Ibrọ̄hīm,
قَدۡ صَدَّقۡتَ ٱلرُّءۡيَآۚ إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Open ayah 37:105o kúkú ti mú àlá náà ṣẹ. Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ ٱلۡبَلَٰٓؤُاْ ٱلۡمُبِينُ
Open ayah 37:106Dájúdájú èyí, òhun ni àdánwò pọ́nńbélé.
وَفَدَيۡنَٰهُ بِذِبۡحٍ عَظِيمٖ
Open ayah 37:107A sì fi àgbò ńlá ṣèràpadà rẹ̀.
وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ
Open ayah 37:108A tún fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
سَلَٰمٌ عَلَىٰٓ إِبۡرَٰهِيمَ
Open ayah 37:109Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm.
كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Open ayah 37:110Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Open ayah 37:111Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
وَبَشَّرۡنَٰهُ بِإِسۡحَٰقَ نَبِيّٗا مِّنَ ٱلصَّٰلِحِينَ
Open ayah 37:112A tún fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ’Ishāƙ, (ó máa jẹ́) Ànábì. (Ó sì máa wà) nínú àwọn ẹni rere.
وَبَٰرَكۡنَا عَلَيۡهِ وَعَلَىٰٓ إِسۡحَٰقَۚ وَمِن ذُرِّيَّتِهِمَا مُحۡسِنٞ وَظَالِمٞ لِّنَفۡسِهِۦ مُبِينٞ
Open ayah 37:113Àti pé A fún òun àti ’Ishāƙ ní ìbùkún. Ẹni rere àti alábòsí pọ́nńbélé (tó ń ṣàbòsí sí) ẹ̀mí ara rẹ̀ wà nínú àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì.[1]
- Bẹ̀rẹ̀ láti āyah 100 títí dé āyah 113, ó ti hàn kedere pé: (ìkíní) Ànábì ’Ismā‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni àkọ́bí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a -; (ìkejì) Ànábì ’Ismā‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni ẹni tí Allāhu Ẹlẹ́dàá pa láṣẹ pé kí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a - pa láti fi jọ́sìn fún Òun; (ìkẹta) Kò sí ohun tó jẹmọ́ ẹ̀jẹ́ àti ìmúṣẹ ẹ̀jẹ́ nínú àlá àti ìṣẹ̀lẹ̀ náà; (ìkẹrin) Ìkíní kejì àwọn ọmọ méjèèjì náà ni ẹni ìbùkún. Àmọ́, àwọn nasọ̄rọ̄, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti àṣà wọn, orúkọ burúkú ni wọ́n ń fún Ànábì ’Ismā‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Hūd; 11:71.
وَلَقَدۡ مَنَنَّا عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ
Open ayah 37:114Dájúdájú A ṣoore fún (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.
وَنَجَّيۡنَٰهُمَا وَقَوۡمَهُمَا مِنَ ٱلۡكَرۡبِ ٱلۡعَظِيمِ
Open ayah 37:115A gba àwọn méjèèjì àti ìjọ àwọn méjèèjì là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá náà.
وَنَصَرۡنَٰهُمۡ فَكَانُواْ هُمُ ٱلۡغَٰلِبِينَ
Open ayah 37:116A tún ṣàrànṣe fún wọn. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olùborí (ọ̀tá wọn).
وَءَاتَيۡنَٰهُمَا ٱلۡكِتَٰبَ ٱلۡمُسۡتَبِينَ
Open ayah 37:117A sì fún àwọn méjèèjì ní Tírà tó yanjú.
وَهَدَيۡنَٰهُمَا ٱلصِّرَٰطَ ٱلۡمُسۡتَقِيمَ
Open ayah 37:118A tún fi àwọn méjèèjì mọ̀nà tààrà.
وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِمَا فِي ٱلۡأٓخِرِينَ
Open ayah 37:119A fún àwọn méjèèjì ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
سَلَٰمٌ عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ
Open ayah 37:120Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Open ayah 37:121Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
إِنَّهُمَا مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Open ayah 37:122Dájúdájú àwọn méjèèjì wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
وَإِنَّ إِلۡيَاسَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Open ayah 37:123Dájúdájú (Ànábì) ’Ilyās wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
إِذۡ قَالَ لِقَوۡمِهِۦٓ أَلَا تَتَّقُونَ
Open ayah 37:124(Ẹ rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù Allāhu ni?
أَتَدۡعُونَ بَعۡلٗا وَتَذَرُونَ أَحۡسَنَ ٱلۡخَٰلِقِينَ
Open ayah 37:125Ṣé ẹ óò máa pe òrìṣà kan, ẹ sì máa fi Ẹni tó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá sílẹ̀?[1]
- Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mu’minūn; 23:14.
ٱللَّهَ رَبَّكُمۡ وَرَبَّ ءَابَآئِكُمُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Open ayah 37:126(ẹ̀ ń fi) Allāhu (sílẹ̀), Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́?”
فَكَذَّبُوهُ فَإِنَّهُمۡ لَمُحۡضَرُونَ
Open ayah 37:127Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, wọ́n máa mú wọn wá sínú Iná.
إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ
Open ayah 37:128Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).
وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ
Open ayah 37:129A fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
سَلَٰمٌ عَلَىٰٓ إِلۡ يَاسِينَ
Open ayah 37:130Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ilyās.
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Open ayah 37:131Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Open ayah 37:132Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
وَإِنَّ لُوطٗا لَّمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Open ayah 37:133Dájúdájú (Ànábì) Lūt wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
إِذۡ نَجَّيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥٓ أَجۡمَعِينَ
Open ayah 37:134(Ẹ rántí) nígbà tí A gba òun àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ là.
إِلَّا عَجُوزٗا فِي ٱلۡغَٰبِرِينَ
Open ayah 37:135Àyàfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́).[1]
- Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26:171.
ثُمَّ دَمَّرۡنَا ٱلۡأٓخَرِينَ
Open ayah 37:136Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run.
وَإِنَّكُمۡ لَتَمُرُّونَ عَلَيۡهِم مُّصۡبِحِينَ
Open ayah 37:137Dájúdájú ẹ̀yin náà kúkú ń gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá láàárọ̀-láàárọ̀
وَبِٱلَّيۡلِۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ
Open ayah 37:138àti ní alaalẹ́. Ṣé ẹ kò níí ṣe làákàyè ni?
وَإِنَّ يُونُسَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Open ayah 37:139Dájúdájú (Ànábì) Yūnus kúkú wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
إِذۡ أَبَقَ إِلَى ٱلۡفُلۡكِ ٱلۡمَشۡحُونِ
Open ayah 37:140(Ẹ rántí) nígbà tí ó sá lọ sínú ọkọ̀ ojú-omi tó kún (fún èrò).
فَسَاهَمَ فَكَانَ مِنَ ٱلۡمُدۡحَضِينَ
Open ayah 37:141Ó sì bá wọn ṣe kúríà papọ̀. Ó sì wà nínú àwọn tí kúrìá já.[1]
- Ìyẹn ni pé, nígbà tí ọkọ̀ ojú-omi fẹ́ yí dànù láààrin agbami odò nítorí èrò àkúnfàya, ọ̀rọ̀ jẹmọ́ kí ẹnì kan kúrò nínú rẹ̀ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo wọn máa bá omi lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣe ƙur‘ah. Ìyẹn ni pé, wọ́n kọ, bí àpẹ̀ẹrẹ, “orúkọ” olúkùlùkù sára n̄ǹkan kan ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Wọ́n sì kó gbogbo rẹ̀ papọ̀ sínú n̄ǹkan kan bí igbá. Wọ́n sì yan ẹnì kan láààrin wọn pé kí ó mú ẹyọ kan péré nínú rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹnukò wọn pé, ẹni tí wọ́n bá mú “orúkọ” rẹ̀ jáde ni wọ́n máa já jù sínú omi odò nítorí kí èrò ọkọ̀ lè fà fún ìtẹ̀síwájú lórí ìrìn náà. Èyí tí wọ́n kọ orúkọ Ànábì Yūnus - kí ọlà Allāhu máa bá a - sí lára ní ọwọ́ ẹni náà bà. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n jù ú sínú odò. Ó sì ṣe wẹ́kú ẹnu ẹja.
فَٱلۡتَقَمَهُ ٱلۡحُوتُ وَهُوَ مُلِيمٞ
Open ayah 37:142Nítorí náà, ẹja gbé e mì; ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi.
فَلَوۡلَآ أَنَّهُۥ كَانَ مِنَ ٱلۡمُسَبِّحِينَ
Open ayah 37:143Nítorí náà, tí kò bá jẹ́ pé ó wà nínú àwọn olùṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu,
لَلَبِثَ فِي بَطۡنِهِۦٓ إِلَىٰ يَوۡمِ يُبۡعَثُونَ
Open ayah 37:144dájúdájú ìbá wà nínú ẹja títí di ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde.
۞فَنَبَذۡنَٰهُ بِٱلۡعَرَآءِ وَهُوَ سَقِيمٞ
Open ayah 37:145Nítorí náà, A jù ú sí orí ilẹ́ gban̄sasa létí omi. Ó sì jẹ́ aláìlera.
وَأَنۢبَتۡنَا عَلَيۡهِ شَجَرَةٗ مِّن يَقۡطِينٖ
Open ayah 37:146A sì mú igi Yẹƙtīn hù jáde láti ṣíji bò ó.
وَأَرۡسَلۡنَٰهُ إِلَىٰ مِاْئَةِ أَلۡفٍ أَوۡ يَزِيدُونَ
Open ayah 37:147A tún rán an níṣẹ́ sí ọ̀kẹ́ márùn-ún (ènìyàn) tàbí kí wọ́n lékún sí i.[1]
- Ọ̀kẹ́ márùn-ún ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún (100,000). Wàyí, àwọn nasọ̄rọ̄ lérò pé, Allāhu kò nímọ̀ nípa pàtó òǹkà ìjọ Ànábì Yūnus - kí ọlà Allāhu máa bá a - l’Ó fi mú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ wá pẹ̀lú “ ’ao” - “tàbí”. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá. Nítorí náà, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:74 fún àlàyé lórí rẹ̀.
فَـَٔامَنُواْ فَمَتَّعۡنَٰهُمۡ إِلَىٰ حِينٖ
Open ayah 37:148Wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo. A sì fún wọn ní ìgbádùn títí di ìgbà díẹ̀.
فَٱسۡتَفۡتِهِمۡ أَلِرَبِّكَ ٱلۡبَنَاتُ وَلَهُمُ ٱلۡبَنُونَ
Open ayah 37:149Bi wọ́n léèrè wò pé: “Ṣé Olúwa rẹ l’ó ni àwọn ọmọbìnrin, tiwọn sì ni ọmọkùnrin?
أَمۡ خَلَقۡنَا ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ إِنَٰثٗا وَهُمۡ شَٰهِدُونَ
Open ayah 37:150Tàbí A dá àwọn mọlāika ní obìnrin, tí àwọn sì jẹ́ ẹlẹ́rìí?”
أَلَآ إِنَّهُم مِّنۡ إِفۡكِهِمۡ لَيَقُولُونَ
Open ayah 37:151Gbọ́, nínú irọ́ wọn ni pé dájúdájú wọ́n ń wí pé:
وَلَدَ ٱللَّهُ وَإِنَّهُمۡ لَكَٰذِبُونَ
Open ayah 37:152“Allāhu bímọ.” Dájúdájú òpùrọ́ sì ni wọ́n.
أَصۡطَفَى ٱلۡبَنَاتِ عَلَى ٱلۡبَنِينَ
Open ayah 37:153Ṣé (Allāhu) ṣẹ̀ṣà àwọn ọmọbìnrin lórí àwọn ọmọkùnrin ni?
مَا لَكُمۡ كَيۡفَ تَحۡكُمُونَ
Open ayah 37:154Kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí?
أَفَلَا تَذَكَّرُونَ
Open ayah 37:155Ṣé ẹ kò níí lo ìrántí ni?
أَمۡ لَكُمۡ سُلۡطَٰنٞ مُّبِينٞ
Open ayah 37:156Tàbí ẹ ní ẹ̀rí tó yanjú lọ́wọ́ ni?
فَأۡتُواْ بِكِتَٰبِكُمۡ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ
Open ayah 37:157Ẹ mú tírà yín wà nígbà náà tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
وَجَعَلُواْ بَيۡنَهُۥ وَبَيۡنَ ٱلۡجِنَّةِ نَسَبٗاۚ وَلَقَدۡ عَلِمَتِ ٱلۡجِنَّةُ إِنَّهُمۡ لَمُحۡضَرُونَ
Open ayah 37:158Wọ́n tún fi ìbátan sáààrin (Allāhu) àti àlùjànnú! Àwọn àlùjànnú sì ti mọ̀ pé, dájúdájú wọ́n kúkú máa mú àwọn wá sínú Iná ni.
سُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ عَمَّا يَصِفُونَ
Open ayah 37:159Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).
إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ
Open ayah 37:160Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).
فَإِنَّكُمۡ وَمَا تَعۡبُدُونَ
Open ayah 37:161Dájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún (lẹ́yìn Allāhu),
مَآ أَنتُمۡ عَلَيۡهِ بِفَٰتِنِينَ
Open ayah 37:162ẹ kò lè fi ṣi ẹnì kan kan lọ́nà
إِلَّا مَنۡ هُوَ صَالِ ٱلۡجَحِيمِ
Open ayah 37:163àfi ẹni tí ó bá fẹ́ wọ inú iná Jẹhīm.
وَمَا مِنَّآ إِلَّا لَهُۥ مَقَامٞ مَّعۡلُومٞ
Open ayah 37:164Kò sí ẹnì kan nínú àwa (mọlāika) àfi kí ó ní ibùdúró tí wọ́n ti mọ̀.
وَإِنَّا لَنَحۡنُ ٱلصَّآفُّونَ
Open ayah 37:165Dájúdájú àwa, a kúkú wà ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ni.
وَإِنَّا لَنَحۡنُ ٱلۡمُسَبِّحُونَ
Open ayah 37:166Àti pé dájúdájú àwa, àwa kúkú ni olùṣàfọ̀mọ́ (fún Allāhu).
وَإِن كَانُواْ لَيَقُولُونَ
Open ayah 37:167Wọ́n kúkú ń wí pé:
لَوۡ أَنَّ عِندَنَا ذِكۡرٗا مِّنَ ٱلۡأَوَّلِينَ
Open ayah 37:168“Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú a bá ní (tírà) ìrántí kan nínú (àwọn tírà) àwọn ẹni àkọ́kọ́,
لَكُنَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ
Open ayah 37:169dájúdájú àwa ìbá jẹ́ ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).”
فَكَفَرُواْ بِهِۦۖ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ
Open ayah 37:170Ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú (Allāhu). Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
وَلَقَدۡ سَبَقَتۡ كَلِمَتُنَا لِعِبَادِنَا ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Open ayah 37:171Dájúdájú ọ̀rọ̀ Wa ti ṣíwájú fún àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn Òjíṣẹ́.
إِنَّهُمۡ لَهُمُ ٱلۡمَنصُورُونَ
Open ayah 37:172Dájúdájú àwọn, àwọn l’a kúkú máa ṣàrànṣe fún.
وَإِنَّ جُندَنَا لَهُمُ ٱلۡغَٰلِبُونَ
Open ayah 37:173Àti pé dájúdájú àwọn ọmọ ogun Wa, àwọn kúkú ni olùborí.
فَتَوَلَّ عَنۡهُمۡ حَتَّىٰ حِينٖ
Open ayah 37:174Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn fún ìgbà díẹ̀.
وَأَبۡصِرۡهُمۡ فَسَوۡفَ يُبۡصِرُونَ
Open ayah 37:175Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò.
أَفَبِعَذَابِنَا يَسۡتَعۡجِلُونَ
Open ayah 37:176Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú?
فَإِذَا نَزَلَ بِسَاحَتِهِمۡ فَسَآءَ صَبَاحُ ٱلۡمُنذَرِينَ
Open ayah 37:177Nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ sí gbàgede wọn, òwúrọ̀ ọjọ́ náà yó sì burú fún àwọn ẹni-akìlọ̀-fún.
وَتَوَلَّ عَنۡهُمۡ حَتَّىٰ حِينٖ
Open ayah 37:178Kúrò lọ́dọ̀ wọn títí di ìgbà kan ná.
وَأَبۡصِرۡ فَسَوۡفَ يُبۡصِرُونَ
Open ayah 37:179Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò.
سُبۡحَٰنَ رَبِّكَ رَبِّ ٱلۡعِزَّةِ عَمَّا يَصِفُونَ
Open ayah 37:180Mímọ́ ni fún Olúwa rẹ, Olúwa (tó ni) agbára, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).
وَسَلَٰمٌ عَلَى ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Open ayah 37:181Kí àlàáfíà máa bá àwọn Òjíṣẹ́
وَٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Open ayah 37:182Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.