طه
Taa-Haa
Translation: Yoruba - Abu Rahima Mikhail Aikweiny · Open the surah
بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
Tọ̄ hā. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
- Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.
مَآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡقُرۡءَانَ لِتَشۡقَىٰٓ
Open ayah 20:2A kò sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún ọ láti kó wàhálà bá ọ.
إِلَّا تَذۡكِرَةٗ لِّمَن يَخۡشَىٰ
Open ayah 20:3Bí kò ṣe pé ó jẹ́ ìrántí fún ẹni tó ń páyà (Allāhu).
تَنزِيلٗا مِّمَّنۡ خَلَقَ ٱلۡأَرۡضَ وَٱلسَّمَٰوَٰتِ ٱلۡعُلَى
Open ayah 20:4(Ó jẹ́) ìmísí tó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹni tí Ó dá ilẹ̀ àti àwọn sánmọ̀ gíga.
ٱلرَّحۡمَٰنُ عَلَى ٱلۡعَرۡشِ ٱسۡتَوَىٰ
Open ayah 20:5Àjọkẹ́-ayé gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá.
لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا وَمَا تَحۡتَ ٱلثَّرَىٰ
Open ayah 20:6TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀, ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì àti ohunkóhun tó wà lábẹ́ ilẹ̀.
وَإِن تَجۡهَرۡ بِٱلۡقَوۡلِ فَإِنَّهُۥ يَعۡلَمُ ٱلسِّرَّ وَأَخۡفَى
Open ayah 20:7Tí o bá sọ ọ̀rọ̀ jáde, dájúdájú (Allāhu) mọ ìkọ̀kọ̀ àti ohun tí ó (tún) pamọ́ jùlọ.
ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ لَهُ ٱلۡأَسۡمَآءُ ٱلۡحُسۡنَىٰ
Open ayah 20:8Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. TiRẹ̀ ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ.
وَهَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ مُوسَىٰٓ
Open ayah 20:9Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā dé ọ̀dọ̀ rẹ?
إِذۡ رَءَا نَارٗا فَقَالَ لِأَهۡلِهِ ٱمۡكُثُوٓاْ إِنِّيٓ ءَانَسۡتُ نَارٗا لَّعَلِّيٓ ءَاتِيكُم مِّنۡهَا بِقَبَسٍ أَوۡ أَجِدُ عَلَى ٱلنَّارِ هُدٗى
Open ayah 20:10(Rántí) nígbà tí ó rí iná kan, ó sọ fún àwọn ará ilé rẹ̀ pé: “Ẹ dúró síbí. Dájúdájú èmi rí iná kan. Ó ṣeé ṣe kí n̄g rí ògúnná mú wá fún yín nínú rẹ̀ tàbí kí n̄g rí ojú ọ̀nà kan nítòsí iná náà.”
فَلَمَّآ أَتَىٰهَا نُودِيَ يَٰمُوسَىٰٓ
Open ayah 20:11Nígbà tí ó dé ibẹ̀, A pè é “Mūsā,
إِنِّيٓ أَنَا۠ رَبُّكَ فَٱخۡلَعۡ نَعۡلَيۡكَ إِنَّكَ بِٱلۡوَادِ ٱلۡمُقَدَّسِ طُوٗى
Open ayah 20:12Dájúdájú Èmi ni Olúwa rẹ. Nítorí náà, bọ́ bàtà rẹ méjèèjì sílẹ̀.[1] Dájúdájú ìwọ wà ní àfonífojì mímọ́, Tuwā.
- Ìdí tí Allāhu - tó ga jùlọ - fi pa á láṣẹ fún Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - láti bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọmọ Mọs‘ūd - kí Allāhu yọ́nú sí i - ṣe gbà á wá ni pé, awọ òkúǹbete kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí wọn kò pa lósè ni wọ́n fi ṣe bàtà náà. Àmọ́ nínú sunnah Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, mùsùlùmí lè wọ bàtà kírun níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ti pa awọ rẹ̀ lósè, tí kò sì níí kó ìnira bá ẹnikẹ́ni lórí ìrun, tí kò sì níí kó ìdọ̀tí wọ inú mọ́sálásí. Ọ̀kan nínú ìrun tí èyí lè ti rọrùn jùlọ ni ìrun tí a kí ní orí ilẹ̀ gban̄sasa bí mọ́sálásí eléruku, ìrun ‘Īd méjèèjì, ìrun jannāzah àti ìrun ìwá òjò.
وَأَنَا ٱخۡتَرۡتُكَ فَٱسۡتَمِعۡ لِمَا يُوحَىٰٓ
Open ayah 20:13Àti pé Èmi ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Nítorí náà, fi etí sí ohun tí A máa fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìmísí.
إِنَّنِيٓ أَنَا ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنَا۠ فَٱعۡبُدۡنِي وَأَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَ لِذِكۡرِيٓ
Open ayah 20:14Dájúdájú Èmi ni Allāhu. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Èmi. Nítorí náà, jọ́sìn fún Mi. Kí o sì kírun fún ìrántí Mi.[1]
- Láti ọ̀dọ̀ ’Anas bun Mọ̄lik, ó sọ pé. Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé: “Tí ọ̀kan nínú yín bá sùn tayọ (àsìkò) ìrun tàbí ó gbàgbé (ìrun) rẹ̀, kí ó kí i nígbà tí ó bá rántí rẹ̀, nítorí pé Allāhu sọ pé: “Kírun fún ìrántí Mi.”
إِنَّ ٱلسَّاعَةَ ءَاتِيَةٌ أَكَادُ أُخۡفِيهَا لِتُجۡزَىٰ كُلُّ نَفۡسِۭ بِمَا تَسۡعَىٰ
Open ayah 20:15Dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀. Ó súnmọ́ kí N̄g ṣàfi hàn[1] rẹ̀ (pẹ̀lú àwọn àmì kan. Àkókò náà wà fún) kí Á lè san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san n̄ǹkan tí ó ṣe níṣẹ́.
- Ẹ kíyè sí ọ̀rọ̀ yìí “’ukfī, ’ikfā’.” Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ alójú-lódì. Nítorí náà, bí ó ṣe túmọ̀ sí ṣíṣe àfihàn n̄ǹkan, ó tún ń túmọ̀ sí fífi n̄ǹkan pamọ́.
فَلَا يَصُدَّنَّكَ عَنۡهَا مَن لَّا يُؤۡمِنُ بِهَا وَٱتَّبَعَ هَوَىٰهُ فَتَرۡدَىٰ
Open ayah 20:16Nítorí náà, ẹni tí kò gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí ó sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó ṣẹ́rí rẹ kúrò níbẹ̀, kí o má baà parun.
وَمَا تِلۡكَ بِيَمِينِكَ يَٰمُوسَىٰ
Open ayah 20:17Kí ni ìyẹn lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ, Mūsā?”
قَالَ هِيَ عَصَايَ أَتَوَكَّؤُاْ عَلَيۡهَا وَأَهُشُّ بِهَا عَلَىٰ غَنَمِي وَلِيَ فِيهَا مَـَٔارِبُ أُخۡرَىٰ
Open ayah 20:18Ó sọ pé: “Ọ̀pá mi ni. Mò ń fi rọ̀gbọ̀kú. Mo tún ń fi já ewé fún àwọn àgùtàn mi. Mo sì tún ń lò ó fún àwọn bùkátà mìíràn.”
قَالَ أَلۡقِهَا يَٰمُوسَىٰ
Open ayah 20:19(Allāhu) sọ pé: “Jù ú sílẹ̀, Mūsā.”
فَأَلۡقَىٰهَا فَإِذَا هِيَ حَيَّةٞ تَسۡعَىٰ
Open ayah 20:20Nígbà náà, ó jù ú sílẹ̀. Ó sì di ejò tó ń sáré.
قَالَ خُذۡهَا وَلَا تَخَفۡۖ سَنُعِيدُهَا سِيرَتَهَا ٱلۡأُولَىٰ
Open ayah 20:21(Allāhu) sọ pé: “Mú un dání, má sì ṣe bẹ̀rù. A máa dá a padà sí ìrísí rẹ̀ àkọ́kọ́.
وَٱضۡمُمۡ يَدَكَ إِلَىٰ جَنَاحِكَ تَخۡرُجۡ بَيۡضَآءَ مِنۡ غَيۡرِ سُوٓءٍ ءَايَةً أُخۡرَىٰ
Open ayah 20:22Fi ọwọ́ rẹ mọ́ (abẹ́) apá rẹ, ó máa jáde ní funfun, tí kì í ṣe taburú. (Ó tún jẹ́) àmì mìíràn.
لِنُرِيَكَ مِنۡ ءَايَٰتِنَا ٱلۡكُبۡرَى
Open ayah 20:23Kí Á lè fi èyí tó tóbi nínú àwọn àmì Wa hàn ọ́.
ٱذۡهَبۡ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ إِنَّهُۥ طَغَىٰ
Open ayah 20:24Lọ sí ọ̀dọ̀ Fir‘aon. Dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-ààlà.”
قَالَ رَبِّ ٱشۡرَحۡ لِي صَدۡرِي
Open ayah 20:25(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, ṣí ọkàn mi payá fún mi.
وَيَسِّرۡ لِيٓ أَمۡرِي
Open ayah 20:26Ṣọ̀rọ̀ mi dìrọ̀rùn fún mi.
وَٱحۡلُلۡ عُقۡدَةٗ مِّن لِّسَانِي
Open ayah 20:27Tú kókó orí ahọ́n mi
يَفۡقَهُواْ قَوۡلِي
Open ayah 20:28kí wọ́n máa gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yé.
وَٱجۡعَل لِّي وَزِيرٗا مِّنۡ أَهۡلِي
Open ayah 20:29Àti pé fún mi ní amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nínú àwọn ará ilé mi,
هَٰرُونَ أَخِي
Open ayah 20:30Hārūn, arákùnrin mi ni.
ٱشۡدُدۡ بِهِۦٓ أَزۡرِي
Open ayah 20:31Fi kún mi lọ́wọ́.
وَأَشۡرِكۡهُ فِيٓ أَمۡرِي
Open ayah 20:32Fi ṣakẹgbẹ́ mi nínú iṣẹ́ mi
كَيۡ نُسَبِّحَكَ كَثِيرٗا
Open ayah 20:33torí kí á lè ṣàfọ̀mọ́ (orúkọ) Rẹ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀,
وَنَذۡكُرَكَ كَثِيرًا
Open ayah 20:34kí á tún lè ṣèrántí Rẹ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.
إِنَّكَ كُنتَ بِنَا بَصِيرٗا
Open ayah 20:35Dájúdájú Ìwọ ń rí wa.”
قَالَ قَدۡ أُوتِيتَ سُؤۡلَكَ يَٰمُوسَىٰ
Open ayah 20:36(Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú A ti fún ọ ní ìbéèrè rẹ, Mūsā.
وَلَقَدۡ مَنَنَّا عَلَيۡكَ مَرَّةً أُخۡرَىٰٓ
Open ayah 20:37Àti pé dájúdájú A ti ṣe oore fún ọ nígbà kan rí.
إِذۡ أَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰٓ أُمِّكَ مَا يُوحَىٰٓ
Open ayah 20:38(Rántí) nígbà tí A ṣípayá ohun tí A ṣípayá fún ìyá rẹ
أَنِ ٱقۡذِفِيهِ فِي ٱلتَّابُوتِ فَٱقۡذِفِيهِ فِي ٱلۡيَمِّ فَلۡيُلۡقِهِ ٱلۡيَمُّ بِٱلسَّاحِلِ يَأۡخُذۡهُ عَدُوّٞ لِّي وَعَدُوّٞ لَّهُۥۚ وَأَلۡقَيۡتُ عَلَيۡكَ مَحَبَّةٗ مِّنِّي وَلِتُصۡنَعَ عَلَىٰ عَيۡنِيٓ
Open ayah 20:39pé: “Ju Mūsā sínú àpótí. Kí o sì gbé e jù sínú odò. Odò yó sì gbé e jù sí etí odò. Ọ̀tá Mi àti ọ̀tá rẹ̀ sì máa gbé e.” Mo sì da ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ Mi bò ọ́ nítorí kí wọ́n lè tọ́jú rẹ lójú Mi.”
إِذۡ تَمۡشِيٓ أُخۡتُكَ فَتَقُولُ هَلۡ أَدُلُّكُمۡ عَلَىٰ مَن يَكۡفُلُهُۥۖ فَرَجَعۡنَٰكَ إِلَىٰٓ أُمِّكَ كَيۡ تَقَرَّ عَيۡنُهَا وَلَا تَحۡزَنَۚ وَقَتَلۡتَ نَفۡسٗا فَنَجَّيۡنَٰكَ مِنَ ٱلۡغَمِّ وَفَتَنَّٰكَ فُتُونٗاۚ فَلَبِثۡتَ سِنِينَ فِيٓ أَهۡلِ مَدۡيَنَ ثُمَّ جِئۡتَ عَلَىٰ قَدَرٖ يَٰمُوسَىٰ
Open ayah 20:40(Rántí) nígbà tí arábìnrin rẹ ń rìn lọ, ó sì ń sọ pé: “Ṣé kí n̄g júwe yín sí ẹni tí ó máa gbà á tọ́?” A sì dá ọ padà sọ́dọ̀ ìyá rẹ nítorí kí ó lè ní ìtutù ojú, àti pé kí ò má baà banújẹ́. Àti pé o pa ẹ̀mí ẹnì kan. A sì mú ọ kúrò nínú ìbànújẹ́. A tún mú àwọn àdánwò kan bá ọ. O tún lo àwọn ọdún kan lọ́dọ̀ àwọn ará Mọdyan. Lẹ́yìn náà, o dé (ní àkókò) tí ó ti wà nínú kádàrá, Mūsā.
وَٱصۡطَنَعۡتُكَ لِنَفۡسِي
Open ayah 20:41Mo sì ṣà ọ́ lẹ́ṣà fún (iṣẹ́) Mi.
ٱذۡهَبۡ أَنتَ وَأَخُوكَ بِـَٔايَٰتِي وَلَا تَنِيَا فِي ذِكۡرِي
Open ayah 20:42Lọ, ìwọ àti arákùnrin rẹ pẹ̀lú àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) Mi. Kí ẹ sì má ṣe kọ́lẹ níbi ìrántí Mi.
ٱذۡهَبَآ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ إِنَّهُۥ طَغَىٰ
Open ayah 20:43Ẹ lọ bá Fir‘aon. Dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-ààlà.
فَقُولَا لَهُۥ قَوۡلٗا لَّيِّنٗا لَّعَلَّهُۥ يَتَذَكَّرُ أَوۡ يَخۡشَىٰ
Open ayah 20:44Ẹ sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀lẹ̀ fún un. Ó ṣeé ṣe kí ó lo ìṣítí tàbí kí ó páyà (Mi).”
قَالَا رَبَّنَآ إِنَّنَا نَخَافُ أَن يَفۡرُطَ عَلَيۡنَآ أَوۡ أَن يَطۡغَىٰ
Open ayah 20:45Àwọn méjèèjì sọ pé: “Olúwa wa, dájúdájú àwa ń páyà pé ó má yára jẹ wá níyà tàbí pé ó má tayọ ẹnu-ààlà.”
قَالَ لَا تَخَافَآۖ إِنَّنِي مَعَكُمَآ أَسۡمَعُ وَأَرَىٰ
Open ayah 20:46(Allāhu) sọ pé: “Ẹ má ṣe páyà. Dájúdájú Èmi wà pẹ̀lú ẹ̀yin méjèèjì; Mò ń gbọ (yín), Mo sì ń ri (yín).”[1]
- Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mujādilah 58:7.
فَأۡتِيَاهُ فَقُولَآ إِنَّا رَسُولَا رَبِّكَ فَأَرۡسِلۡ مَعَنَا بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ وَلَا تُعَذِّبۡهُمۡۖ قَدۡ جِئۡنَٰكَ بِـَٔايَةٖ مِّن رَّبِّكَۖ وَٱلسَّلَٰمُ عَلَىٰ مَنِ ٱتَّبَعَ ٱلۡهُدَىٰٓ
Open ayah 20:47Nítorí náà, ẹ lọ bá a, kí ẹ sọ fún un pé: “Dájúdájú Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ ni àwa méjèèjì. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá wa lọ. Má ṣe fìyà jẹ wọ́n. Dájúdájú a ti mú àmì kan wá bá ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Kí àlàáfíà sì máa bá ẹni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà náà.
إِنَّا قَدۡ أُوحِيَ إِلَيۡنَآ أَنَّ ٱلۡعَذَابَ عَلَىٰ مَن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ
Open ayah 20:48Dájúdájú wọ́n ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí wa pé, dájúdájú ìyà ń bẹ fún ẹni tí ó bá pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i.”
قَالَ فَمَن رَّبُّكُمَا يَٰمُوسَىٰ
Open ayah 20:49(Fir‘aon) wí pé: “Ta ni Olúwa ẹ̀yin méjèèjì, Mūsā?”
قَالَ رَبُّنَا ٱلَّذِيٓ أَعۡطَىٰ كُلَّ شَيۡءٍ خَلۡقَهُۥ ثُمَّ هَدَىٰ
Open ayah 20:50(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa wa ni Ẹni tí Ó fún gbogbo n̄ǹkan ní ìṣẹ̀dá rẹ̀.[1] Lẹ́yìn náà, Ó tọ́ ọ sí ọ̀nà.”
- Ìyẹn ni pé, Allāhu Ẹlẹ́dàá ṣẹ̀dá ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú àwòrán àti àdámọ́ tó máa ṣe wẹ́kú jíjẹ́ ẹ̀dá rẹ̀, tí ó sì máa yà á sọ́tọ̀ láààrin àwọn ẹ̀dá mìíràn. Nítorí náà, ènìyàn ń jẹ́ ènìyàn lórí àwòrán àti àdámọ́ tó ṣe wẹ́kú ènìyàn, àlùjànnú ń jẹ́ àlùjànnú lórí àwòrán àti àdámọ́ tó ṣe wẹ́kú àlùjànnú, mọlāika ń jẹ́ mọlāika lórí àwòrán àti àdámọ́ tó ṣe wẹ́kú mọlāika, ẹranko ń jẹ́ ẹranko lórí àwòrán àti àdámọ́ tó ṣe wẹ́kú ẹranko, kòkòrò ń jẹ́ kòkòrò lórí àwòrán àti àdámọ́ tó ṣe wẹ́kú kòkòrò, sánmọ̀ ń jẹ́ sánmọ̀ lórí àwòrán àti àdámọ́ tó ṣe wẹ́kú sánmọ̀, ilẹ̀ ń jẹ́ ilẹ̀ lórí àwòrán àti àdámọ́ tó ṣe wẹ́kú ilẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bákan náà, ènìyàn jọra wọn, àmọ́ ènìyàn kò jọ ẹ̀dá mìíràn. Àlùjànnú jọra wọn, àmọ́ àlùjànnú kò jọ ẹ̀dá mìíràn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́yìn náà, Allāhu Afinimọ̀nà tọ́ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan sọ́nà lórí ọ̀nà tí ó máa gbà lo ẹ̀yà ara rẹ̀. Tí ẹnì kan bá wá sọ pé Allāhu dá ènìyàn lórí àwòrán Ara Rẹ̀, ó ti sọ ìsọkúsọ. Ẹnì kan kò sì níí sọ bẹ́ẹ̀ àfi aláìgbàgbọ́ nínú pàápàá bíbẹ Allāhu èyí tí kò jọ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá kan kan.
قَالَ فَمَا بَالُ ٱلۡقُرُونِ ٱلۡأُولَىٰ
Open ayah 20:51(Fir‘aon) wí pé: “Kí ló mú àwọn ìran àkọ́kọ́ (tí wọn kò fi mọ̀nà)?”
قَالَ عِلۡمُهَا عِندَ رَبِّي فِي كِتَٰبٖۖ لَّا يَضِلُّ رَبِّي وَلَا يَنسَى
Open ayah 20:52(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ìmọ̀ rẹ̀ wà nínú tírà kan lọ́dọ̀ Olúwa mi. Olúwa mi kò níí ṣàṣìṣe. Kò sì níí gbàgbé.
ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَرۡضَ مَهۡدٗا وَسَلَكَ لَكُمۡ فِيهَا سُبُلٗا وَأَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَخۡرَجۡنَا بِهِۦٓ أَزۡوَٰجٗا مِّن نَّبَاتٖ شَتَّىٰ
Open ayah 20:53(Òun ni) Ẹni tí Ó tẹ́ ilẹ̀ ní pẹrẹsẹ fún yín. Ó sì la àwọn ọ̀nà sínú rẹ̀ fún yín. Ó sì sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. A sì fi mú oríṣiríṣi jáde nínú àwọn irúgbìn ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
كُلُواْ وَٱرۡعَوۡاْ أَنۡعَٰمَكُمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّأُوْلِي ٱلنُّهَىٰ
Open ayah 20:54Ẹ jẹ, kí ẹ sì fi bọ́ àwọn ẹran-ọ̀sìn yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onílàákàyè.
۞مِنۡهَا خَلَقۡنَٰكُمۡ وَفِيهَا نُعِيدُكُمۡ وَمِنۡهَا نُخۡرِجُكُمۡ تَارَةً أُخۡرَىٰ
Open ayah 20:55Láti ara erùpẹ̀ ni A ti da yín. Inú rẹ̀ sì ni A óò da yín padà sí. Láti inú rẹ̀ sì ni A óò ti mu yín jáde padà nígbà mìíràn.”
وَلَقَدۡ أَرَيۡنَٰهُ ءَايَٰتِنَا كُلَّهَا فَكَذَّبَ وَأَبَىٰ
Open ayah 20:56Dájúdájú A ti fi àwọn àmì Wa hàn án, gbogbo rẹ̀. Àmọ́ ó pè é ní irọ́. Ó sì kọ̀ jálẹ̀.
قَالَ أَجِئۡتَنَا لِتُخۡرِجَنَا مِنۡ أَرۡضِنَا بِسِحۡرِكَ يَٰمُوسَىٰ
Open ayah 20:57Ó wí pé: “Ṣé o wá bá wa nítorí kí o lè mú wa jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa pẹ̀lú idán rẹ ni, Mūsā?
فَلَنَأۡتِيَنَّكَ بِسِحۡرٖ مِّثۡلِهِۦ فَٱجۡعَلۡ بَيۡنَنَا وَبَيۡنَكَ مَوۡعِدٗا لَّا نُخۡلِفُهُۥ نَحۡنُ وَلَآ أَنتَ مَكَانٗا سُوٗى
Open ayah 20:58Dájúdájú a máa mú idán irú rẹ̀ wá bá ọ. Nítorí náà, mú àyè àdéhùn ìpàdé láààrin àwa àti ìwọ, tí àwa àti ìwọ kò sì níí yapa rẹ̀, (kí ó jẹ́) àyè kan tí kò níí fì sọ́dọ̀ igun méjèèjì.”
قَالَ مَوۡعِدُكُمۡ يَوۡمُ ٱلزِّينَةِ وَأَن يُحۡشَرَ ٱلنَّاسُ ضُحٗى
Open ayah 20:59(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Àkókò ìpàdé yín ni ọjọ́ Ọ̀ṣọ́ (ìyẹn, ọjọ́ ọdún). Kí wọ́n sì kó àwọn ènìyàn jọ ní ìyálẹ̀ta.”
فَتَوَلَّىٰ فِرۡعَوۡنُ فَجَمَعَ كَيۡدَهُۥ ثُمَّ أَتَىٰ
Open ayah 20:60Fir‘aon pẹ̀yìndà. Ó sì sa ète rẹ̀ jọ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, ó dé (síbẹ̀).
قَالَ لَهُم مُّوسَىٰ وَيۡلَكُمۡ لَا تَفۡتَرُواْ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبٗا فَيُسۡحِتَكُم بِعَذَابٖۖ وَقَدۡ خَابَ مَنِ ٱفۡتَرَىٰ
Open ayah 20:61(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ègbé yín ò! Ẹ má ṣe dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu nítorí kí Ó má baà fi ìyà pa yín rẹ́. Àti pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá dá àdápa irọ́ (mọ́ Allāhu) ti pòfo.”
فَتَنَٰزَعُوٓاْ أَمۡرَهُم بَيۡنَهُمۡ وَأَسَرُّواْ ٱلنَّجۡوَىٰ
Open ayah 20:62Wọ́n fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ láààrin ara wọn. Wọ́n sì tẹ̀ sọ̀rọ̀.
قَالُوٓاْ إِنۡ هَٰذَٰنِ لَسَٰحِرَٰنِ يُرِيدَانِ أَن يُخۡرِجَاكُم مِّنۡ أَرۡضِكُم بِسِحۡرِهِمَا وَيَذۡهَبَا بِطَرِيقَتِكُمُ ٱلۡمُثۡلَىٰ
Open ayah 20:63Wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwọn méjèèjì yìí, òpìdán ni wọ́n o. Wọ́n fẹ́ mu yín jáde kúrò lórí ilẹ̀ yín pẹ̀lú idán wọn ni. Wọ́n sì (fẹ́) gba ojú ọ̀nà yín tó dára jùlọ mọ yín lọ́wọ́.
فَأَجۡمِعُواْ كَيۡدَكُمۡ ثُمَّ ٱئۡتُواْ صَفّٗاۚ وَقَدۡ أَفۡلَحَ ٱلۡيَوۡمَ مَنِ ٱسۡتَعۡلَىٰ
Open ayah 20:64Nítorí náà, ẹ kó ète yín jọ papọ̀ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, kí ẹ tò wá ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Dájúdájú ẹni tí ó bá borí ní òní ti jèrè.”
قَالُواْ يَٰمُوسَىٰٓ إِمَّآ أَن تُلۡقِيَ وَإِمَّآ أَن نَّكُونَ أَوَّلَ مَنۡ أَلۡقَىٰ
Open ayah 20:65(Àwọn òpìdán) wí pé: “Mūsā, ìwọ ni o máa kọ́kọ́ ju (ọ̀pá sílẹ̀ ni) tàbí àwa ni a óò kọ́kọ́ jù ú sílẹ̀.”
قَالَ بَلۡ أَلۡقُواْۖ فَإِذَا حِبَالُهُمۡ وَعِصِيُّهُمۡ يُخَيَّلُ إِلَيۡهِ مِن سِحۡرِهِمۡ أَنَّهَا تَسۡعَىٰ
Open ayah 20:66(Mūsā) sọ pé: “Ẹ ju (tiyín) sílẹ̀ (ná).” Nígbà náà ni àwọn okùn wọn àti ọ̀pá wọn bá ń yíra padà lójú rẹ̀ nípasẹ̀ idán wọn, bí ẹni pé dájúdájú wọ́n ń sáré.
فَأَوۡجَسَ فِي نَفۡسِهِۦ خِيفَةٗ مُّوسَىٰ
Open ayah 20:67Ìbẹ̀rù wọn sì mú (Ànábì) Mūsā.[1]
- Tàbí “(Ànábì) Mūsā pa ìbẹ̀rù wọn mọ́ra”.
قُلۡنَا لَا تَخَفۡ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡأَعۡلَىٰ
Open ayah 20:68A sọ pé: “Má ṣe páyà. Dájúdájú ìwọ, ìwọ lo máa lékè.
وَأَلۡقِ مَا فِي يَمِينِكَ تَلۡقَفۡ مَا صَنَعُوٓاْۖ إِنَّمَا صَنَعُواْ كَيۡدُ سَٰحِرٖۖ وَلَا يُفۡلِحُ ٱلسَّاحِرُ حَيۡثُ أَتَىٰ
Open ayah 20:69Ju ohun tí ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ sílẹ̀. Ó sì máa gbé ohun tí wọ́n ṣe kalẹ̀ mì káló. Dájúdájú ohun tí wọ́n ṣe kalẹ̀, ète òpìdán ni. Òpìdán kò sì níí jèrè ní ibikíbi tí ó bá dé.”
فَأُلۡقِيَ ٱلسَّحَرَةُ سُجَّدٗا قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِرَبِّ هَٰرُونَ وَمُوسَىٰ
Open ayah 20:70Nítorí náà, iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wó lulẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu). Wọ́n wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Olúwa Hārūn àti Mūsā.”
قَالَ ءَامَنتُمۡ لَهُۥ قَبۡلَ أَنۡ ءَاذَنَ لَكُمۡۖ إِنَّهُۥ لَكَبِيرُكُمُ ٱلَّذِي عَلَّمَكُمُ ٱلسِّحۡرَۖ فَلَأُقَطِّعَنَّ أَيۡدِيَكُمۡ وَأَرۡجُلَكُم مِّنۡ خِلَٰفٖ وَلَأُصَلِّبَنَّكُمۡ فِي جُذُوعِ ٱلنَّخۡلِ وَلَتَعۡلَمُنَّ أَيُّنَآ أَشَدُّ عَذَابٗا وَأَبۡقَىٰ
Open ayah 20:71(Fir‘aon) wí pé: “Ṣé ẹ ti gbàfà fún un ṣíwájú kí èmi tó yọ̀ǹda fún yín? Dájúdájú òun ni àgbà yín tí ó kọ yín ní idán pípa. Nítorí náà, dájúdájú mo máa gé àwọn ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Dájúdájú mo tún máa kàn yín mọ́ àwọn igi dàbínù. Dájúdájú ẹ̀yin yóò mọ èwo nínú wa ni ìyà (rẹ̀) yóò le jùlọ, tí ó sì máa pẹ́ jùlọ.”
قَالُواْ لَن نُّؤۡثِرَكَ عَلَىٰ مَا جَآءَنَا مِنَ ٱلۡبَيِّنَٰتِ وَٱلَّذِي فَطَرَنَاۖ فَٱقۡضِ مَآ أَنتَ قَاضٍۖ إِنَّمَا تَقۡضِي هَٰذِهِ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَآ
Open ayah 20:72(Àwọn òpìdán) sọ pé: “Àwa kò níí gbọ́lá fún ọ lórí ohun tí ó dé bá wa nínú àwọn ẹ̀rí tó dájú, (a kò sì níí gbọ́lá fún ọ lórí) Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá wa. Nítorí náà, dá ohun tí ó bá fẹ́ dá ní ẹjọ́. Ilé ayé yìí nìkan ni o ti lè dájọ́.
إِنَّآ ءَامَنَّا بِرَبِّنَا لِيَغۡفِرَ لَنَا خَطَٰيَٰنَا وَمَآ أَكۡرَهۡتَنَا عَلَيۡهِ مِنَ ٱلسِّحۡرِۗ وَٱللَّهُ خَيۡرٞ وَأَبۡقَىٰٓ
Open ayah 20:73Dájúdájú àwa gbàgbọ́ nínú Olúwa wa nítorí kí Ó lè ṣe àforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún wa àti ohun tí o jẹ wá nípá ṣe nínú idán pípa. Allāhu lóore jùlọ, Ó sì máa wà títí láéláé.
إِنَّهُۥ مَن يَأۡتِ رَبَّهُۥ مُجۡرِمٗا فَإِنَّ لَهُۥ جَهَنَّمَ لَا يَمُوتُ فِيهَا وَلَا يَحۡيَىٰ
Open ayah 20:74Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá wá bá Olúwa rẹ̀ ní (ipò) ẹlẹ́ṣẹ̀, dájúdájú iná Jahanamọ ti wà fún un. Kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí wà lààyè.
وَمَن يَأۡتِهِۦ مُؤۡمِنٗا قَدۡ عَمِلَ ٱلصَّٰلِحَٰتِ فَأُوْلَٰٓئِكَ لَهُمُ ٱلدَّرَجَٰتُ ٱلۡعُلَىٰ
Open ayah 20:75Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wá bá A (ní ipò) onígbàgbọ́ òdodo, tí ó sì ti ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn ipò gíga ń bẹ fún.
جَنَّٰتُ عَدۡنٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ وَذَٰلِكَ جَزَآءُ مَن تَزَكَّىٰ
Open ayah 20:76(Ohun ni) àwọn Ọgbà ìdẹ̀ra gbére tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni ẹ̀san fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (iṣẹ́ rẹ̀).”
وَلَقَدۡ أَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰٓ أَنۡ أَسۡرِ بِعِبَادِي فَٱضۡرِبۡ لَهُمۡ طَرِيقٗا فِي ٱلۡبَحۡرِ يَبَسٗا لَّا تَخَٰفُ دَرَكٗا وَلَا تَخۡشَىٰ
Open ayah 20:77Àti pé dájúdájú A ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā báyìí pé: “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní òru. Fi (ọ̀pá rẹ) na omi fún wọn (kí ó di) ojú ọ̀nà gbígbẹ kan nínú omi òkun.[1] O ò níí bẹ̀rù àlébá, o ò sì níí páyà (ìtẹ̀rì sínú omi òkun).”
- Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:50.
فَأَتۡبَعَهُمۡ فِرۡعَوۡنُ بِجُنُودِهِۦ فَغَشِيَهُم مِّنَ ٱلۡيَمِّ مَا غَشِيَهُمۡ
Open ayah 20:78Fir‘aon sì tẹ̀lé wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ohun tí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru nínú odò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru.
وَأَضَلَّ فِرۡعَوۡنُ قَوۡمَهُۥ وَمَا هَدَىٰ
Open ayah 20:79Fir‘aon ṣi àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́nà; òun (náà) kò sì mọ̀nà.
يَٰبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ قَدۡ أَنجَيۡنَٰكُم مِّنۡ عَدُوِّكُمۡ وَوَٰعَدۡنَٰكُمۡ جَانِبَ ٱلطُّورِ ٱلۡأَيۡمَنَ وَنَزَّلۡنَا عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَنَّ وَٱلسَّلۡوَىٰ
Open ayah 20:80Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, dájúdájú A ti gbà yín là lọ́wọ́ ọ̀tá yín. A sì ṣe àdéhùn fún yín (pé kí Ànábì Mūsā wá, kí Á bá a sọ̀rọ̀ tààrà) ní ẹ̀gbẹ́ àpáta ní ọwọ́ ọ̀tún[1] (Ànábì Mūsā láààrin àpáta àti àfonífojì[2] ní ìwọ̀ òòrùn[3]). A sì sọ ohun mímu mọnu àti ohun jíjẹ salwā kalẹ̀ fún yín. [4]
كُلُواْ مِن طَيِّبَٰتِ مَا رَزَقۡنَٰكُمۡ وَلَا تَطۡغَوۡاْ فِيهِ فَيَحِلَّ عَلَيۡكُمۡ غَضَبِيۖ وَمَن يَحۡلِلۡ عَلَيۡهِ غَضَبِي فَقَدۡ هَوَىٰ
Open ayah 20:81Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pa lésè fún yín. Ẹ má sì kọjá ẹnu ààlà nínú rẹ̀ nítorí kí ìbínú Mi má baà kò le yín lórí. Ẹnikẹ́ni tí ìbínú Mi bá sì kò lé lórí, dájúdájú ó ti jábọ́ (sínú ìparun).
وَإِنِّي لَغَفَّارٞ لِّمَن تَابَ وَءَامَنَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا ثُمَّ ٱهۡتَدَىٰ
Open ayah 20:82Dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, lẹ́yìn náà tí ó tún tẹ̀lé ìmọ̀nà.
۞وَمَآ أَعۡجَلَكَ عَن قَوۡمِكَ يَٰمُوسَىٰ
Open ayah 20:83Kí ni ó mú ọ kánjú ya àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, Mūsā?
قَالَ هُمۡ أُوْلَآءِ عَلَىٰٓ أَثَرِي وَعَجِلۡتُ إِلَيۡكَ رَبِّ لِتَرۡضَىٰ
Open ayah 20:84Ó sọ pé: “Àwọn nìwọ̀nyí tí wọ́n ń tọ orípa mi bọ̀ (lẹ́yìn mi). Èmi sì kánjú wá sọ́dọ̀ Rẹ nítorí kí O lè yọ́nú sí mi ni, Olúwa mi.”
قَالَ فَإِنَّا قَدۡ فَتَنَّا قَوۡمَكَ مِنۢ بَعۡدِكَ وَأَضَلَّهُمُ ٱلسَّامِرِيُّ
Open ayah 20:85(Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú Àwa ti dán ìjọ rẹ wò lẹ́yìn rẹ. Àti pé Sāmiriy ṣì wọ́n lọ́nà.”
فَرَجَعَ مُوسَىٰٓ إِلَىٰ قَوۡمِهِۦ غَضۡبَٰنَ أَسِفٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ أَلَمۡ يَعِدۡكُمۡ رَبُّكُمۡ وَعۡدًا حَسَنًاۚ أَفَطَالَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡعَهۡدُ أَمۡ أَرَدتُّمۡ أَن يَحِلَّ عَلَيۡكُمۡ غَضَبٞ مِّن رَّبِّكُمۡ فَأَخۡلَفۡتُم مَّوۡعِدِي
Open ayah 20:86(Ànábì) Mūsā sì padà sọ́dọ̀ ìjọ rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú àti ìbànújẹ́. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ṣé Olúwa yín kò ti ba yín ṣe àdéhùn dáadáa ni? Ṣé àdéhùn ti pẹ́ jù lójú yín ni tàbí ẹ fẹ́ kí ìbínú kò le yín lórí láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ẹ fi yapa àdéhùn mi?”
قَالُواْ مَآ أَخۡلَفۡنَا مَوۡعِدَكَ بِمَلۡكِنَا وَلَٰكِنَّا حُمِّلۡنَآ أَوۡزَارٗا مِّن زِينَةِ ٱلۡقَوۡمِ فَقَذَفۡنَٰهَا فَكَذَٰلِكَ أَلۡقَى ٱلسَّامِرِيُّ
Open ayah 20:87Wọ́n wí pé: “Àwa kò fínnúfíndọ̀ yapa àdéhùn fúnra wa, ṣùgbọ́n wọ́n di ẹrù ọ̀ṣọ́ àwọn ènìyàn (Misrọ) rù wá lọ́rùn. A sì jù ú sínú iná (pẹ̀lú àṣẹ Sāmiriyy). Báyẹn náà sì ni Sāmiriyy ṣe ju tirẹ̀.”
فَأَخۡرَجَ لَهُمۡ عِجۡلٗا جَسَدٗا لَّهُۥ خُوَارٞ فَقَالُواْ هَٰذَآ إِلَٰهُكُمۡ وَإِلَٰهُ مُوسَىٰ فَنَسِيَ
Open ayah 20:88Ó sì (fi mọ) ọmọ màálù ọ̀bọrọgidi kan jáde fún wọn, tó ń dún (bíi màálù). Wọ́n sì wí pé: “Èyí ni ọlọ́hun yín àti ọlọ́hun Mūsā. Àmọ́ ó ti gbàgbé (rẹ̀).”
أَفَلَا يَرَوۡنَ أَلَّا يَرۡجِعُ إِلَيۡهِمۡ قَوۡلٗا وَلَا يَمۡلِكُ لَهُمۡ ضَرّٗا وَلَا نَفۡعٗا
Open ayah 20:89Ṣé wọn kò rí i pé kò lè dá èsì ọ̀rọ̀ kan padà fún wọn ni, kò sì ní agbára láti kó ìnira tàbí àǹfààní kan bá wọn!
وَلَقَدۡ قَالَ لَهُمۡ هَٰرُونُ مِن قَبۡلُ يَٰقَوۡمِ إِنَّمَا فُتِنتُم بِهِۦۖ وَإِنَّ رَبَّكُمُ ٱلرَّحۡمَٰنُ فَٱتَّبِعُونِي وَأَطِيعُوٓاْ أَمۡرِي
Open ayah 20:90Àti pé dájúdájú Hārūn ti sọ fún wọn ṣíwájú pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, wọ́n kàn fi ṣe àdánwò fún yín ni. Dájúdájú Olúwa yín ni Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé mi. Kí ẹ sì tẹ̀lé àṣẹ mi.”
قَالُواْ لَن نَّبۡرَحَ عَلَيۡهِ عَٰكِفِينَ حَتَّىٰ يَرۡجِعَ إِلَيۡنَا مُوسَىٰ
Open ayah 20:91Wọ́n wí pé: “A ò níí yé dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ tí a óò máa jọ́sìn fún un títí (Ànábì) Mūsā yóò fi padà sọ́dọ̀ wa.”
قَالَ يَٰهَٰرُونُ مَا مَنَعَكَ إِذۡ رَأَيۡتَهُمۡ ضَلُّوٓاْ
Open ayah 20:92(Ànábì) Mūsā sọ pé: “Hārūn, kí ni ó kọ̀ fún ọ nígbà tí o rí wọn tí wọ́n ṣìnà
أَلَّا تَتَّبِعَنِۖ أَفَعَصَيۡتَ أَمۡرِي
Open ayah 20:93láti tọ̀ mí wá? Ṣé o yapa àṣẹ mi ni?”
قَالَ يَبۡنَؤُمَّ لَا تَأۡخُذۡ بِلِحۡيَتِي وَلَا بِرَأۡسِيٓۖ إِنِّي خَشِيتُ أَن تَقُولَ فَرَّقۡتَ بَيۡنَ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ وَلَمۡ تَرۡقُبۡ قَوۡلِي
Open ayah 20:94(Ànábì Hārūn) sọ pé: “Ọmọ ìyá mi, má ṣe fi irungbọ̀n mi mú mi, (má ṣe fi irun) orí mi mú mi. Dájúdájú èmi páyà pé ó máa sọ pé: 'O dá òpínyà sílẹ̀ láààrin àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. O ò sì ṣọ́ ọ̀rọ̀ mi.'“
قَالَ فَمَا خَطۡبُكَ يَٰسَٰمِرِيُّ
Open ayah 20:95(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Kí ni ọ̀rọ̀ tìrẹ ti jẹ́, Sāmiriyy?”
قَالَ بَصُرۡتُ بِمَا لَمۡ يَبۡصُرُواْ بِهِۦ فَقَبَضۡتُ قَبۡضَةٗ مِّنۡ أَثَرِ ٱلرَّسُولِ فَنَبَذۡتُهَا وَكَذَٰلِكَ سَوَّلَتۡ لِي نَفۡسِي
Open ayah 20:96(Sāmiriyy) wí pé: “Mo rí ohun tí wọn kò rí. Mo sì bu ẹ̀kúnwọ́ kan níbi (erùpẹ̀) ojú ẹsẹ̀ (ẹṣin) Òjíṣẹ́ (ìyẹn, mọlāika Jibrīl). Mo sì dà á sílẹ̀ (láti fi mọ ère). Báyẹn ni ẹ̀mí mi ṣe (aburú) ní ọ̀ṣọ́ fún mi.”
قَالَ فَٱذۡهَبۡ فَإِنَّ لَكَ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ أَن تَقُولَ لَا مِسَاسَۖ وَإِنَّ لَكَ مَوۡعِدٗا لَّن تُخۡلَفَهُۥۖ وَٱنظُرۡ إِلَىٰٓ إِلَٰهِكَ ٱلَّذِي ظَلۡتَ عَلَيۡهِ عَاكِفٗاۖ لَّنُحَرِّقَنَّهُۥ ثُمَّ لَنَنسِفَنَّهُۥ فِي ٱلۡيَمِّ نَسۡفًا
Open ayah 20:97(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Nítorí náà, máa lọ. Dájúdájú (ìjìyà) rẹ nílé ayé yìí ni kí o máa wí pé, “Má fi ara kàn mí”. Àti pé dájúdájú ọjọ́ ìyà kan ń bẹ fún ọ tí wọn kò níí gbé fò ọ́. Kí o sì wo ọlọ́hun rẹ, èyí tí o takú tì lọ́rùn tí ò ń bọ, dájúdájú a máa dáná sun ún. Lẹ́yìn náà, dájúdájú a máa ku eérú rẹ̀ dànù pátápátá sínú odò.
إِنَّمَآ إِلَٰهُكُمُ ٱللَّهُ ٱلَّذِي لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۚ وَسِعَ كُلَّ شَيۡءٍ عِلۡمٗا
Open ayah 20:98Ọlọ́hun yín ni Allāhu nìkan, ẹni tí kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ó fi ìmọ̀ gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan.
كَذَٰلِكَ نَقُصُّ عَلَيۡكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ مَا قَدۡ سَبَقَۚ وَقَدۡ ءَاتَيۡنَٰكَ مِن لَّدُنَّا ذِكۡرٗا
Open ayah 20:99Báyẹn ni A ṣe ń sọ ìtàn fún ọ nínú àwọn ìró tí ó ti ṣíwájú. Láti ọ̀dọ̀ Wa sì ni A kúkú ti fún ọ ní ìrántí (ìyẹn, al-Ƙur’ān).
مَّنۡ أَعۡرَضَ عَنۡهُ فَإِنَّهُۥ يَحۡمِلُ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وِزۡرًا
Open ayah 20:100Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbẹ̀, dájúdájú ó máa ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde.
خَٰلِدِينَ فِيهِۖ وَسَآءَ لَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ حِمۡلٗا
Open ayah 20:101Olùṣegbére ni wọ́n nínú (ìyà) rẹ̀. (Ẹrù ẹ̀ṣẹ̀) sì burú fún wọn láti rù ní Ọjọ́ Àjíǹde.
يَوۡمَ يُنفَخُ فِي ٱلصُّورِۚ وَنَحۡشُرُ ٱلۡمُجۡرِمِينَ يَوۡمَئِذٖ زُرۡقٗا
Open ayah 20:102Ní ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. A sí máa kó àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jọ ní ọjọ́ yẹn, tí ojú wọn yó sì dúdú batakun.
يَتَخَٰفَتُونَ بَيۡنَهُمۡ إِن لَّبِثۡتُمۡ إِلَّا عَشۡرٗا
Open ayah 20:103Wọn yó sì máa sọ̀rọ̀ ní jẹ́ẹ́jẹ́ láààrin ara wọn pé: “Ẹ̀yin kò gbé ilé ayé tayọ (ọjọ́) mẹ́wàá.”
نَّحۡنُ أَعۡلَمُ بِمَا يَقُولُونَ إِذۡ يَقُولُ أَمۡثَلُهُمۡ طَرِيقَةً إِن لَّبِثۡتُمۡ إِلَّا يَوۡمٗا
Open ayah 20:104Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń wí nígbà tí ẹni tí ọpọlọ rẹ̀ pé jùlọ nínú wọn wí pé: “Ẹ kò gbé ilé ayé tayọ ọjọ́ kan.”
وَيَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلۡجِبَالِ فَقُلۡ يَنسِفُهَا رَبِّي نَسۡفٗا
Open ayah 20:105Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa àwọn àpáta. Sọ pé: “Olúwa mi yóò kù wọ́n dànù pátápátá.
فَيَذَرُهَا قَاعٗا صَفۡصَفٗا
Open ayah 20:106Nígbà náà, Ó máa fi wọ́n sílẹ̀ ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ gban̄sasa.
لَّا تَرَىٰ فِيهَا عِوَجٗا وَلَآ أَمۡتٗا
Open ayah 20:107O ò sì níí rí ọ̀gbun tàbí gelemọ kan nínú rẹ̀.
يَوۡمَئِذٖ يَتَّبِعُونَ ٱلدَّاعِيَ لَا عِوَجَ لَهُۥۖ وَخَشَعَتِ ٱلۡأَصۡوَاتُ لِلرَّحۡمَٰنِ فَلَا تَسۡمَعُ إِلَّا هَمۡسٗا
Open ayah 20:108Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ènìyàn yóò tẹ̀lé olùpèpè náà, kò níí sí yíyà kúrò lẹ́yìn rẹ̀. Àwọn ohùn yó sì palọ́lọ́ fún Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, o ò níí gbọ́ ohùn kan bí kò ṣe gìrìgìrì ẹsẹ̀.
يَوۡمَئِذٖ لَّا تَنفَعُ ٱلشَّفَٰعَةُ إِلَّا مَنۡ أَذِنَ لَهُ ٱلرَّحۡمَٰنُ وَرَضِيَ لَهُۥ قَوۡلٗا
Open ayah 20:109Ní ọjọ́ yẹn, ìṣìpẹ̀ kò níí ṣe àǹfààní àfi ẹni tí Àjọkẹ́-ayé bá yọ̀ǹda fún, tí Ó sì yọ́nú sí ọ̀rọ̀ fún un.[1]
- Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:48.
يَعۡلَمُ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُمۡ وَلَا يُحِيطُونَ بِهِۦ عِلۡمٗا
Open ayah 20:110(Allāhu) mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wọn. Àwọn kò sì fi ìmọ̀ rọkiri ká Rẹ̀.
۞وَعَنَتِ ٱلۡوُجُوهُ لِلۡحَيِّ ٱلۡقَيُّومِۖ وَقَدۡ خَابَ مَنۡ حَمَلَ ظُلۡمٗا
Open ayah 20:111Àwọn ojú yó sì wólẹ̀ fún Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá. Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá di àbòsí mẹ́rù ti pòfo.
وَمَن يَعۡمَلۡ مِنَ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَلَا يَخَافُ ظُلۡمٗا وَلَا هَضۡمٗا
Open ayah 20:112Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nínú àwọn iṣẹ́ rere, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, kí ó má ṣe páyà àbòsí tàbí ìrẹ́jẹ kan (láti ọ̀dọ̀ Allāhu).
وَكَذَٰلِكَ أَنزَلۡنَٰهُ قُرۡءَانًا عَرَبِيّٗا وَصَرَّفۡنَا فِيهِ مِنَ ٱلۡوَعِيدِ لَعَلَّهُمۡ يَتَّقُونَ أَوۡ يُحۡدِثُ لَهُمۡ ذِكۡرٗا
Open ayah 20:113Báyẹn ni A ṣe sọ (ìrántí) kalẹ̀ ní ohun kíké pẹ̀lú èdè Lárúbáwá. A sì ṣe àlàyé oníran-ànran ìlérí sínú rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ṣọ́ra (fún ìyà) tàbí nítorí kí ó lè jẹ́ ìrántí fún wọn.
فَتَعَٰلَى ٱللَّهُ ٱلۡمَلِكُ ٱلۡحَقُّۗ وَلَا تَعۡجَلۡ بِٱلۡقُرۡءَانِ مِن قَبۡلِ أَن يُقۡضَىٰٓ إِلَيۡكَ وَحۡيُهُۥۖ وَقُل رَّبِّ زِدۡنِي عِلۡمٗا
Open ayah 20:114Nítorí náà, Allāhu Ọba Òdodo ga jùlọ. Má ṣe kánjú pẹ̀lú al-Ƙur’ān ṣíwájú kí wọ́n tó parí ìmísí rẹ̀ fún ọ. Kí o sì sọ pé: “Olúwa mi, ṣàlékún ìmọ̀ fún mi.”
وَلَقَدۡ عَهِدۡنَآ إِلَىٰٓ ءَادَمَ مِن قَبۡلُ فَنَسِيَ وَلَمۡ نَجِدۡ لَهُۥ عَزۡمٗا
Open ayah 20:115Dájúdájú A ṣe àdéhùn fún (Ànábì) Ādam ṣíwájú. Ṣùgbọ́n ó gbàgbé. A kò sì bá a pẹ̀lú ìpinnu ọkàn.
وَإِذۡ قُلۡنَا لِلۡمَلَٰٓئِكَةِ ٱسۡجُدُواْ لِأٓدَمَ فَسَجَدُوٓاْ إِلَّآ إِبۡلِيسَ أَبَىٰ
Open ayah 20:116Nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí Ādam. Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs, (tí) ó kọ̀.”
فَقُلۡنَا يَٰٓـَٔادَمُ إِنَّ هَٰذَا عَدُوّٞ لَّكَ وَلِزَوۡجِكَ فَلَا يُخۡرِجَنَّكُمَا مِنَ ٱلۡجَنَّةِ فَتَشۡقَىٰٓ
Open ayah 20:117Nítorí náà, A sọ pé: “Ādam, dájúdájú èyí ni ọ̀tá fún ìwọ àti ìyàwó rẹ. Nítorí náà, kò gbọdọ̀ mú ẹ̀yin méjèèjì jáde kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra nítorí kí o má baà máa dààmú (fún ìjẹ-ìmu).
إِنَّ لَكَ أَلَّا تَجُوعَ فِيهَا وَلَا تَعۡرَىٰ
Open ayah 20:118Dájúdájú ebi kò níí pa ọ́, o ò sì níí rìn hòhò nínú rẹ̀.
وَأَنَّكَ لَا تَظۡمَؤُاْ فِيهَا وَلَا تَضۡحَىٰ
Open ayah 20:119Àti pé dájúdájú òǹgbẹ kò níí gbẹ ọ́ nínú rẹ̀, òòrùn kò sì níí pa ọ́.”
فَوَسۡوَسَ إِلَيۡهِ ٱلشَّيۡطَٰنُ قَالَ يَٰٓـَٔادَمُ هَلۡ أَدُلُّكَ عَلَىٰ شَجَرَةِ ٱلۡخُلۡدِ وَمُلۡكٖ لَّا يَبۡلَىٰ
Open ayah 20:120Ṣùgbọ́n Èṣù kó ròyíròyí bá a; ó wí pé: “Ādam, ǹjẹ́ mo lè júwe rẹ sí igi gbére àti ìjọba tí kò níí tán?”
فَأَكَلَا مِنۡهَا فَبَدَتۡ لَهُمَا سَوۡءَٰتُهُمَا وَطَفِقَا يَخۡصِفَانِ عَلَيۡهِمَا مِن وَرَقِ ٱلۡجَنَّةِۚ وَعَصَىٰٓ ءَادَمُ رَبَّهُۥ فَغَوَىٰ
Open ayah 20:121Nítorí náà, àwọn méjèèjì jẹ nínú (èso) rẹ̀. Ìhòhò àwọn méjèèjì sì hàn síra wọn; àwọn méjèèjì sì bẹ̀rẹ̀ sí da ewé Ọgbà Ìdẹ̀ra bo ara wọn. Ādam yapa àṣẹ Olúwa rẹ̀. Ó sì ṣìnà.
ثُمَّ ٱجۡتَبَٰهُ رَبُّهُۥ فَتَابَ عَلَيۡهِ وَهَدَىٰ
Open ayah 20:122Lẹ́yìn náà, Olúwa rẹ̀ ṣà á lẹ́ṣà; Ó gba ìronúpìwàdà rẹ̀, Ó sì tọ́ ọ sí ọ̀nà.
قَالَ ٱهۡبِطَا مِنۡهَا جَمِيعَۢاۖ بَعۡضُكُمۡ لِبَعۡضٍ عَدُوّٞۖ فَإِمَّا يَأۡتِيَنَّكُم مِّنِّي هُدٗى فَمَنِ ٱتَّبَعَ هُدَايَ فَلَا يَضِلُّ وَلَا يَشۡقَىٰ
Open ayah 20:123(Allāhu) sọ pé: “Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ pátápátá. Apá kan yín sì jẹ́ ọ̀tá sí apá kan - ẹ̀yin àti Èṣù. Nígbà tí ìmọ̀nà bá sì dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Mi, ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà Mi, kò níí ṣìnà, kò sì níí ṣorí burúkú.
وَمَنۡ أَعۡرَضَ عَن ذِكۡرِي فَإِنَّ لَهُۥ مَعِيشَةٗ ضَنكٗا وَنَحۡشُرُهُۥ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ أَعۡمَىٰ
Open ayah 20:124Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣẹ́rí kúrò níbi ìrántí Mi, dájúdájú ìṣẹ̀mí ìnira máa wà fún un. A sì máa gbé e dìde ní afọ́jú ní Ọjọ́ Àjíǹde.”
قَالَ رَبِّ لِمَ حَشَرۡتَنِيٓ أَعۡمَىٰ وَقَدۡ كُنتُ بَصِيرٗا
Open ayah 20:125(Ó) máa wí pé: “Olúwa mi, nítorí kí ni O fi gbé mi dìde ní afọ́jú? Mo ti jẹ́ olùríran tẹ́lẹ̀!”
قَالَ كَذَٰلِكَ أَتَتۡكَ ءَايَٰتُنَا فَنَسِيتَهَاۖ وَكَذَٰلِكَ ٱلۡيَوۡمَ تُنسَىٰ
Open ayah 20:126(Allāhu) sọ pé: “Báyẹn ni àwọn āyah Wa ṣe dé bá ọ, o sì gbàgbé rẹ̀ (o pa á tì). Ní òní, báyẹn ni wọ́n ṣe máa gbàgbé ìwọ náà (sínú Iná).
وَكَذَٰلِكَ نَجۡزِي مَنۡ أَسۡرَفَ وَلَمۡ يُؤۡمِنۢ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِۦۚ وَلَعَذَابُ ٱلۡأٓخِرَةِ أَشَدُّ وَأَبۡقَىٰٓ
Open ayah 20:127Àti pé báyẹn ni A ṣe ń san ẹ̀san fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àṣejù, tí kò sì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Olúwa rẹ̀. Dájúdájú ìyà Ọjọ́ Ìkẹ́yìn le jùlọ. Ó sì máa wà títí láéláé.”
أَفَلَمۡ يَهۡدِ لَهُمۡ كَمۡ أَهۡلَكۡنَا قَبۡلَهُم مِّنَ ٱلۡقُرُونِ يَمۡشُونَ فِي مَسَٰكِنِهِمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّأُوْلِي ٱلنُّهَىٰ
Open ayah 20:128Ṣé kò hàn sí wọn pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parun ṣíwájú wọn, tí (àwọn wọ̀nyí náà) sì ń rìn kọjá ní ibùgbé wọn! Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn olóye.
وَلَوۡلَا كَلِمَةٞ سَبَقَتۡ مِن رَّبِّكَ لَكَانَ لِزَامٗا وَأَجَلٞ مُّسَمّٗى
Open ayah 20:129Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan tó ṣíwájú àti gbèdéke àkókò kan lọ́dọ̀ Olúwa rẹ (ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn) ìbá ti di dandan.
فَٱصۡبِرۡ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ قَبۡلَ طُلُوعِ ٱلشَّمۡسِ وَقَبۡلَ غُرُوبِهَاۖ وَمِنۡ ءَانَآيِٕ ٱلَّيۡلِ فَسَبِّحۡ وَأَطۡرَافَ ٱلنَّهَارِ لَعَلَّكَ تَرۡضَىٰ
Open ayah 20:130Nítorí náà, ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí, kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa Rẹ ṣíwájú yíyọ òòrùn àti ṣíwájú wíwọ̀ rẹ̀. Ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) ní àwọn àsìkò alẹ́ àti ní àwọn abala ọ̀sán nítorí kí (Á lè san ọ́ ní ẹ̀san rere tí) ó máa yọ́nú sí.
وَلَا تَمُدَّنَّ عَيۡنَيۡكَ إِلَىٰ مَا مَتَّعۡنَا بِهِۦٓ أَزۡوَٰجٗا مِّنۡهُمۡ زَهۡرَةَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا لِنَفۡتِنَهُمۡ فِيهِۚ وَرِزۡقُ رَبِّكَ خَيۡرٞ وَأَبۡقَىٰ
Open ayah 20:131Má ṣe fẹjú rẹ sí ohun tí A fi ṣe ìgbádùn tó jẹ́ òdòdó ìṣẹ̀mí ilé ayé fún àwọn ìran-ìran kan nínú wọn. (A fún wọn) nítorí kí Á lè fi ṣe àdánwò fún wọn ni. Arísìkí Olúwa rẹ lóore jùlọ. Ó sì máa wà títí láéláé.
وَأۡمُرۡ أَهۡلَكَ بِٱلصَّلَوٰةِ وَٱصۡطَبِرۡ عَلَيۡهَاۖ لَا نَسۡـَٔلُكَ رِزۡقٗاۖ نَّحۡنُ نَرۡزُقُكَۗ وَٱلۡعَٰقِبَةُ لِلتَّقۡوَىٰ
Open ayah 20:132Pa ará ilé rẹ láṣẹ ìrun kíkí, kí o sì ṣe sùúrù lórí rẹ̀. A ò níí bèèrè èsè kan lọ́wọ́ rẹ; Àwa l’À ń pèsè fún ọ. Ìgbẹ̀yìn rere sì wà fún ìbẹ̀rù (Allāhu).
وَقَالُواْ لَوۡلَا يَأۡتِينَا بِـَٔايَةٖ مِّن رَّبِّهِۦٓۚ أَوَلَمۡ تَأۡتِهِم بَيِّنَةُ مَا فِي ٱلصُّحُفِ ٱلۡأُولَىٰ
Open ayah 20:133Wọ́n wí pé: “Nítorí kí ni kò fi mú àmì kan wá fún wa láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Ṣé ẹ̀rí tó yanjú tó wà nínú àwọn tákàdá àkọ́kọ́ kò dé bá wọn ni?
وَلَوۡ أَنَّآ أَهۡلَكۡنَٰهُم بِعَذَابٖ مِّن قَبۡلِهِۦ لَقَالُواْ رَبَّنَا لَوۡلَآ أَرۡسَلۡتَ إِلَيۡنَا رَسُولٗا فَنَتَّبِعَ ءَايَٰتِكَ مِن قَبۡلِ أَن نَّذِلَّ وَنَخۡزَىٰ
Open ayah 20:134Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú A ti fi ìyà kan pa wọ́n run ṣíwájú rẹ̀ ni, wọn ìbá wí pé: “Olúwa wa nítorí kí ni O ò ṣe rán Òjíṣẹ́ kan sí wa, àwa ìbá tẹ̀lé àwọn āyah Rẹ ṣíwájú kí á tó yẹpẹrẹ, (kí á sì tó) kàbùkù.”
قُلۡ كُلّٞ مُّتَرَبِّصٞ فَتَرَبَّصُواْۖ فَسَتَعۡلَمُونَ مَنۡ أَصۡحَٰبُ ٱلصِّرَٰطِ ٱلسَّوِيِّ وَمَنِ ٱهۡتَدَىٰ
Open ayah 20:135Sọ pé: “Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni olùretí (ìkángun).” Nítorí náà, ẹ máa retí (rẹ̀). Ẹ máa mọ ta ni èrò ọ̀nà tààrà àti ẹni tó mọ̀nà.