المرسلات
Al-Mursalaat
Translation: Yoruba - Abu Rahima Mikhail Aikweiny · Open the surah
بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
وَٱلۡمُرۡسَلَٰتِ عُرۡفٗا
Open ayah 77:1Allāhu fi àwọn atẹ́gùn tó ń sáré ní tẹ̀léǹtẹ̀lé búra.
فَٱلۡعَٰصِفَٰتِ عَصۡفٗا
Open ayah 77:2Ó fi àwọn ìjì atẹ́gùn tó ń jà búra.
وَٱلنَّٰشِرَٰتِ نَشۡرٗا
Open ayah 77:3Ó fi àwọn atẹ́gùn tó ń tú èṣújò ká búra.
فَٱلۡفَٰرِقَٰتِ فَرۡقٗا
Open ayah 77:4Ó fi àwọn tó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́ búra.
فَٱلۡمُلۡقِيَٰتِ ذِكۡرًا
Open ayah 77:5Ó fi àwọn mọlāika tó ń mú ìrántí wá (bá àwọn Òjíṣẹ́) búra.
عُذۡرًا أَوۡ نُذۡرًا
Open ayah 77:6(Ìrántí náà jẹ́) àwíjàre tàbí ìkìlọ̀.
إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَوَٰقِعٞ
Open ayah 77:7Dájúdájú ohun tí A ṣe ní àdéhùn fún yín kúkú máa ṣẹlẹ̀.
فَإِذَا ٱلنُّجُومُ طُمِسَتۡ
Open ayah 77:8Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá pa (ìmọ́lẹ̀) ìràwọ̀ rẹ́,
وَإِذَا ٱلسَّمَآءُ فُرِجَتۡ
Open ayah 77:9àti nígbà tí wọ́n bá ṣí sánmọ̀ sílẹ̀ gbagada,
وَإِذَا ٱلۡجِبَالُ نُسِفَتۡ
Open ayah 77:10àti nígbà tí wọ́n bá ku àwọn àpáta dànù,
وَإِذَا ٱلرُّسُلُ أُقِّتَتۡ
Open ayah 77:11àti nígbà tí wọ́n bá fún àwọn Òjíṣẹ́ ní àsìkò láti kójọ (pẹ̀lú ìjọ wọn),
لِأَيِّ يَوۡمٍ أُجِّلَتۡ
Open ayah 77:12ọjọ́ wo ni wọ́n so (àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí) rọ̀ fún ná?
لِيَوۡمِ ٱلۡفَصۡلِ
Open ayah 77:13Fún ọjọ́ ìpínyà (láààrin àwọn ẹ̀dá) ni.
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلۡفَصۡلِ
Open ayah 77:14Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ìpínyà?
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ
Open ayah 77:15Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
أَلَمۡ نُهۡلِكِ ٱلۡأَوَّلِينَ
Open ayah 77:16Ǹjẹ́ Àwa kò ti pa àwọn ẹni àkọ́kọ́ rẹ́ bí?
ثُمَّ نُتۡبِعُهُمُ ٱلۡأٓخِرِينَ
Open ayah 77:17Lẹ́yìn náà, A sì máa fi àwọn ẹni Ìkẹ́yìn tẹ̀lé wọn (nínú ìparun).
كَذَٰلِكَ نَفۡعَلُ بِٱلۡمُجۡرِمِينَ
Open ayah 77:18Báyẹn ni A ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ
Open ayah 77:19Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
أَلَمۡ نَخۡلُقكُّم مِّن مَّآءٖ مَّهِينٖ
Open ayah 77:20Ṣé A kò ṣẹ̀dá yin láti inú omi lílẹ yẹpẹrẹ bí?
فَجَعَلۡنَٰهُ فِي قَرَارٖ مَّكِينٍ
Open ayah 77:21Lẹ́yìn náà, A fi sínú àyè ààbò (ìyẹn, ilé-ọmọ)
إِلَىٰ قَدَرٖ مَّعۡلُومٖ
Open ayah 77:22títí di gbèdéke àkókò kan tí A ti mọ̀ (ìyen, ọjọ́ ìbímọ).
فَقَدَرۡنَا فَنِعۡمَ ٱلۡقَٰدِرُونَ
Open ayah 77:23A sì ní ìkápá àti àyànmọ́ (lórí rẹ̀. Àwa sì ni) Olùkápá àti Olùpèbùbù ẹ̀dá tó dára.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ
Open ayah 77:24Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
أَلَمۡ نَجۡعَلِ ٱلۡأَرۡضَ كِفَاتًا
Open ayah 77:25Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ohun tó ń kó ẹ̀dá jọ mọ́ra wọn;
أَحۡيَآءٗ وَأَمۡوَٰتٗا
Open ayah 77:26(ìyẹn) àwọn alààyè àti àwọn òkú?
وَجَعَلۡنَا فِيهَا رَوَٰسِيَ شَٰمِخَٰتٖ وَأَسۡقَيۡنَٰكُم مَّآءٗ فُرَاتٗا
Open ayah 77:27A sì fi àwọn àpáta gbagidi gíga-gíga sínú rẹ̀. A sì fún yín ní omi dídùn mu.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ
Open ayah 77:28Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
ٱنطَلِقُوٓاْ إِلَىٰ مَا كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ
Open ayah 77:29Ẹ máa lọ sí ibi tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.
ٱنطَلِقُوٓاْ إِلَىٰ ظِلّٖ ذِي ثَلَٰثِ شُعَبٖ
Open ayah 77:30Ẹ máa lọ sí ibi èéfín ẹlẹ́ka mẹ́ta.
لَّا ظَلِيلٖ وَلَا يُغۡنِي مِنَ ٱللَّهَبِ
Open ayah 77:31Kì í ṣe ibòji tútù. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ìjòfòfò Iná.
إِنَّهَا تَرۡمِي بِشَرَرٖ كَٱلۡقَصۡرِ
Open ayah 77:32Dájúdájú (Iná náà) yóò máa ju ẹ̀tapàrà (rẹ̀ sókè tó máa dà) bí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì.
كَأَنَّهُۥ جِمَٰلَتٞ صُفۡرٞ
Open ayah 77:33(Ó máa dà) bí àwọn ràkúnmí aláwọ̀ omi ọsàn.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ
Open ayah 77:34Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́
هَٰذَا يَوۡمُ لَا يَنطِقُونَ
Open ayah 77:35Èyí ni ọjọ́ tí wọn kò níí sọ̀rọ̀.
وَلَا يُؤۡذَنُ لَهُمۡ فَيَعۡتَذِرُونَ
Open ayah 77:36A kò sì níí yọ̀ǹda (ọ̀rọ̀ sísọ) fún wọn, áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò mú àwáwí wá.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ
Open ayah 77:37Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
هَٰذَا يَوۡمُ ٱلۡفَصۡلِۖ جَمَعۡنَٰكُمۡ وَٱلۡأَوَّلِينَ
Open ayah 77:38Èyí ni ọjọ́ ìpínyà. Àwa yó sì kó ẹ̀yin àti àwọn ẹni àkọ́kọ́ jọ.
فَإِن كَانَ لَكُمۡ كَيۡدٞ فَكِيدُونِ
Open ayah 77:39Tí ẹ bá ní ète kan lọ́wọ́, ẹ déte sí Mi wò.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ
Open ayah 77:40Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
إِنَّ ٱلۡمُتَّقِينَ فِي ظِلَٰلٖ وَعُيُونٖ
Open ayah 77:41Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà níbi ibòji àti àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú,
وَفَوَٰكِهَ مِمَّا يَشۡتَهُونَ
Open ayah 77:42àti àwọn èso èyí tí wọ́n bá ń fẹ́.
كُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ هَنِيٓـَٔۢا بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
Open ayah 77:43Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbádùn nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Open ayah 77:44Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ
Open ayah 77:45Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
كُلُواْ وَتَمَتَّعُواْ قَلِيلًا إِنَّكُم مُّجۡرِمُونَ
Open ayah 77:46Ẹ jẹ, kí ẹ sì gbádùn fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni yín.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ
Open ayah 77:47Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱرۡكَعُواْ لَا يَرۡكَعُونَ
Open ayah 77:48Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé kí wọ́n kírun, wọn kò níí kírun.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ
Open ayah 77:49Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
فَبِأَيِّ حَدِيثِۭ بَعۡدَهُۥ يُؤۡمِنُونَ
Open ayah 77:50Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?[1]
- Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:185.