المدثر
Al-Muddaththir
Translation: Yoruba - Abu Rahima Mikhail Aikweiny · Open the surah
بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡمُدَّثِّرُ
Open ayah 74:1Ìwọ olùdaṣọbora.
قُمۡ فَأَنذِرۡ
Open ayah 74:2Dìde kí o ṣèkìlọ̀.
وَرَبَّكَ فَكَبِّرۡ
Open ayah 74:3Olúwa rẹ sì ni kí o gbé títóbi fún.
وَثِيَابَكَ فَطَهِّرۡ
Open ayah 74:4Aṣọ rẹ ni kí o fọ̀ mọ́.
وَٱلرُّجۡزَ فَٱهۡجُرۡ
Open ayah 74:5Òrìṣà ni kí o jìnnà sí.
وَلَا تَمۡنُن تَسۡتَكۡثِرُ
Open ayah 74:6Má ṣe tọrẹ nítorí kí o lè rí púpọ̀ gbà.
وَلِرَبِّكَ فَٱصۡبِرۡ
Open ayah 74:7Olúwa rẹ ni kí o ṣe sùúrù fún.
فَإِذَا نُقِرَ فِي ٱلنَّاقُورِ
Open ayah 74:8Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde,
فَذَٰلِكَ يَوۡمَئِذٖ يَوۡمٌ عَسِيرٌ
Open ayah 74:9ìyẹn, ní ọjọ́ yẹn, ni ọjọ́ ìnira,
عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ غَيۡرُ يَسِيرٖ
Open ayah 74:10tí kò níí rọrùn fún àwọn aláìgbàgbọ́.
ذَرۡنِي وَمَنۡ خَلَقۡتُ وَحِيدٗا
Open ayah 74:11Fi Mí dá ẹni tí Mo dá ní òun nìkan (ìyẹn nínú ikùn ìyá rẹ̀).
وَجَعَلۡتُ لَهُۥ مَالٗا مَّمۡدُودٗا
Open ayah 74:12Mo sì fún un ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá
وَبَنِينَ شُهُودٗا
Open ayah 74:13àti àwọn ọmọkúnrin tó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀.
وَمَهَّدتُّ لَهُۥ تَمۡهِيدٗا
Open ayah 74:14Mo sì fi àyè ìrọ̀rùn gbá a dáadáa.
ثُمَّ يَطۡمَعُ أَنۡ أَزِيدَ
Open ayah 74:15Lẹ́yìn náà, ó tún ń jẹ̀rankàn pé kí N̄g ṣe àlékún.
كَلَّآۖ إِنَّهُۥ كَانَ لِأٓيَٰتِنَا عَنِيدٗا
Open ayah 74:16Rárá o! Dájúdájú ó jẹ́ alátakò sí àwọn āyah Wa.
سَأُرۡهِقُهُۥ صَعُودًا
Open ayah 74:17Èmi yóò la ìyà pọ́nkèpọ́nkè bọ̀ ọ́ lọ́rùn (nínú Iná)[1].
- Orúkọ àpáta ńlá kan nínú Iná ni Sọ‘ūd. Kèfèrí yóò máa pọ́n òkè náà láààrin àádọ́rin ọdún ní àpọ́njábọ́. Ìdí nìyí tí wọ́n fi pe ìyà náà ní ìyà pọ́nkèpọ́nkè.
إِنَّهُۥ فَكَّرَ وَقَدَّرَ
Open ayah 74:18Dájúdájú ó ronú (lódì nípa al-Ƙur’ān). Ó sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan nínú ẹ̀mí rẹ̀).
فَقُتِلَ كَيۡفَ قَدَّرَ
Open ayah 74:19Wọ́n sì ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu.
ثُمَّ قُتِلَ كَيۡفَ قَدَّرَ
Open ayah 74:20Lẹ́yìn náà, Wọ́n tún ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu.
ثُمَّ نَظَرَ
Open ayah 74:21Lẹ́yìn náà, ó wò sùn.
ثُمَّ عَبَسَ وَبَسَرَ
Open ayah 74:22Lẹ́yìn náà, ó fajú ro, ó sì dijú mágbárí.
ثُمَّ أَدۡبَرَ وَٱسۡتَكۡبَرَ
Open ayah 74:23Lẹ́yìn náà, ó pẹ̀yìndà, ó sì ṣègbéraga.
فَقَالَ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٞ يُؤۡثَرُ
Open ayah 74:24Ó sì wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán àtọwọ́dọ́wọ́.
إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا قَوۡلُ ٱلۡبَشَرِ
Open ayah 74:25Kí ni èyí bí kò ṣe ọ̀rọ̀ abara”
سَأُصۡلِيهِ سَقَرَ
Open ayah 74:26Èmi yóò fi sínú iná Saƙọr.
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا سَقَرُ
Open ayah 74:27Kí l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ iná Saƙọr?
لَا تُبۡقِي وَلَا تَذَرُ
Open ayah 74:28(Saƙọr) kò níí ṣẹ́ ẹ kù, kò sì níí pa á tì.[1]
- Ìyẹn ni pé, Iná náà yóò máa jó o lọ, kò sì níí gba ẹ̀mí rẹ̀.
لَوَّاحَةٞ لِّلۡبَشَرِ
Open ayah 74:29Ó máa jó awọ ara di dúdú.
عَلَيۡهَا تِسۡعَةَ عَشَرَ
Open ayah 74:30(Àwọn mọlāika) mọ́kàndínlógún ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.
وَمَا جَعَلۡنَآ أَصۡحَٰبَ ٱلنَّارِ إِلَّا مَلَٰٓئِكَةٗۖ وَمَا جَعَلۡنَا عِدَّتَهُمۡ إِلَّا فِتۡنَةٗ لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ لِيَسۡتَيۡقِنَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ وَيَزۡدَادَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِيمَٰنٗا وَلَا يَرۡتَابَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡمُؤۡمِنُونَ وَلِيَقُولَ ٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٞ وَٱلۡكَٰفِرُونَ مَاذَآ أَرَادَ ٱللَّهُ بِهَٰذَا مَثَلٗاۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ ٱللَّهُ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِي مَن يَشَآءُۚ وَمَا يَعۡلَمُ جُنُودَ رَبِّكَ إِلَّا هُوَۚ وَمَا هِيَ إِلَّا ذِكۡرَىٰ لِلۡبَشَرِ
Open ayah 74:31Àwa kò ṣe ẹnì kan ní ẹ̀ṣọ́ Iná àfi àwọn mọlāika. Àwa kò sì ṣe òǹkà wọn (bẹ́ẹ̀) bí kò ṣe (nítorí kí ó lè jẹ́) àdánwò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àti nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà lè ní àmọ̀dájú àti nítorí kí àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo lè lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo má baà ṣeyèméjì àti nítorí kí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn àti àwọn aláìgbàgbọ́ lè wí pé: “Kí ni Allāhu gbà lérò pẹ̀lú àpèjúwe yìí?” Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Kò sì sí ẹni tí ó mọ àwọn ọmọ ogun Olúwa rẹ àfi Òun náà. (Iná Saƙọr) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún abara.
كَلَّا وَٱلۡقَمَرِ
Open ayah 74:32Ẹ gbọ́! Allāhu fi òṣùpá búra.
وَٱلَّيۡلِ إِذۡ أَدۡبَرَ
Open ayah 74:33Ó tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá lọ búra.
وَٱلصُّبۡحِ إِذَآ أَسۡفَرَ
Open ayah 74:34Ó tún fi òwúrọ̀ nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́ búra.
إِنَّهَا لَإِحۡدَى ٱلۡكُبَرِ
Open ayah 74:35Dájúdájú (iná Saƙọr) ni ọ̀kan nínú (àwọn àdánwò) tó tóbi.
نَذِيرٗا لِّلۡبَشَرِ
Open ayah 74:36(Ó jẹ́) ìkìlọ̀ fún abara.
لِمَن شَآءَ مِنكُمۡ أَن يَتَقَدَّمَ أَوۡ يَتَأَخَّرَ
Open ayah 74:37Fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti tẹ̀ síwájú tàbí láti fà sẹ́yìn (nínú ẹ̀ṣẹ̀).
كُلُّ نَفۡسِۭ بِمَا كَسَبَتۡ رَهِينَةٌ
Open ayah 74:38Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ni onídùúró fún ohun tó ṣe níṣẹ́.
إِلَّآ أَصۡحَٰبَ ٱلۡيَمِينِ
Open ayah 74:39Àyàfi àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
فِي جَنَّٰتٖ يَتَسَآءَلُونَ
Open ayah 74:40Wọn yóò máa bira wọn léèrè ọ̀rọ̀ nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra
عَنِ ٱلۡمُجۡرِمِينَ
Open ayah 74:41nípa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pé:
مَا سَلَكَكُمۡ فِي سَقَرَ
Open ayah 74:42“Kí ni ó mu yín wọ inú iná Saƙọr?”
قَالُواْ لَمۡ نَكُ مِنَ ٱلۡمُصَلِّينَ
Open ayah 74:43Wọn yóò wí pé: “Àwa kò sí nínú àwọn olùkírun ni.
وَلَمۡ نَكُ نُطۡعِمُ ٱلۡمِسۡكِينَ
Open ayah 74:44Àwa kò sì sí nínú àwọn tó ń bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.
وَكُنَّا نَخُوضُ مَعَ ٱلۡخَآئِضِينَ
Open ayah 74:45Àwa sì máa ń sọ ìsọkúsọ pẹ̀lú àwọn onísọkúsọ.
وَكُنَّا نُكَذِّبُ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ
Open ayah 74:46Àti pé àwa máa ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́
حَتَّىٰٓ أَتَىٰنَا ٱلۡيَقِينُ
Open ayah 74:47títí ikú fi dé bá wa.”
فَمَا تَنفَعُهُمۡ شَفَٰعَةُ ٱلشَّٰفِعِينَ
Open ayah 74:48Ìpẹ̀ àwọn olùṣìpẹ̀ kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní.
فَمَا لَهُمۡ عَنِ ٱلتَّذۡكِرَةِ مُعۡرِضِينَ
Open ayah 74:49Kí ló mú wọn ná tí wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí
كَأَنَّهُمۡ حُمُرٞ مُّسۡتَنفِرَةٞ
Open ayah 74:50bí ẹni pé àwọn ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ń sá lọ,
فَرَّتۡ مِن قَسۡوَرَةِۭ
Open ayah 74:51tó sá fún kìnìhún?
بَلۡ يُرِيدُ كُلُّ ٱمۡرِيٕٖ مِّنۡهُمۡ أَن يُؤۡتَىٰ صُحُفٗا مُّنَشَّرَةٗ
Open ayah 74:52Rárá, ńṣe ni ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń fẹ́ kí Á fún òun náà ní Tírà tí ó máa ṣeé tẹ́ han àwọn ènìyàn (bíi ti al-Ƙur’ān).
كَلَّاۖ بَل لَّا يَخَافُونَ ٱلۡأٓخِرَةَ
Open ayah 74:53Rárá. Wọn kò páyà ọ̀run ni.
كَلَّآ إِنَّهُۥ تَذۡكِرَةٞ
Open ayah 74:54Ẹ gbọ́! Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí.
فَمَن شَآءَ ذَكَرَهُۥ
Open ayah 74:55Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́, kí ó rántí rẹ̀.
وَمَا يَذۡكُرُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُۚ هُوَ أَهۡلُ ٱلتَّقۡوَىٰ وَأَهۡلُ ٱلۡمَغۡفِرَةِ
Open ayah 74:56Wọn kò sì níí rántí (al-Ƙur’ān) àfi tí Allāhu bá fẹ́. (Allāhu) Òun l’a gbọ́dọ̀ bẹ̀rù. Òun l’ó sì ni àforíjìn.