البروج
Al-Burooj
Translation: Yoruba - Abu Rahima Mikhail Aikweiny · Open the surah
بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلۡبُرُوجِ
Open ayah 85:1(Allāhu) fi sánmọ̀ tí àwọn ibùsọ̀ (òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀) wà nínú rẹ̀ búra.
وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡمَوۡعُودِ
Open ayah 85:2Ó tún fi ọjọ́ tí wọ́n ṣe ní àdéhùn (ìyẹn Ọjọ́ Àjíǹde) búra.
وَشَاهِدٖ وَمَشۡهُودٖ
Open ayah 85:3Ó tún fi olùjẹ́rìí àti ohun tó jẹ́rìí sí búra.
قُتِلَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡأُخۡدُودِ
Open ayah 85:4A ṣẹ́bi lé àwọn tó gbẹ́ kòtò (iná),
ٱلنَّارِ ذَاتِ ٱلۡوَقُودِ
Open ayah 85:5(ìyẹn) iná tí wọ́n ń fi igi kò (nínú kòtò).
إِذۡ هُمۡ عَلَيۡهَا قُعُودٞ
Open ayah 85:6(Rántí) nígbà tí wọ́n jókòó sí ìtòsí rẹ̀.
وَهُمۡ عَلَىٰ مَا يَفۡعَلُونَ بِٱلۡمُؤۡمِنِينَ شُهُودٞ
Open ayah 85:7Wọ́n sì ń wo ohun tí wọ́n ń ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
وَمَا نَقَمُواْ مِنۡهُمۡ إِلَّآ أَن يُؤۡمِنُواْ بِٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَمِيدِ
Open ayah 85:8Wọn kò rí àlèébù kan (wọn kò sì kórira kiní kan) lára wọn bí kò ṣe pé, wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, Alágbára, Ẹlẹ́yìn,
ٱلَّذِي لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدٌ
Open ayah 85:9Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan.
إِنَّ ٱلَّذِينَ فَتَنُواْ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ ثُمَّ لَمۡ يَتُوبُواْ فَلَهُمۡ عَذَابُ جَهَنَّمَ وَلَهُمۡ عَذَابُ ٱلۡحَرِيقِ
Open ayah 85:10Dájúdájú àwọn tó fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò ronú pìwàdà, ìyà iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. Ìyà iná tó ń jó sì wà fún wọn.
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُمۡ جَنَّٰتٞ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۚ ذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡكَبِيرُ
Open ayah 85:11Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.
إِنَّ بَطۡشَ رَبِّكَ لَشَدِيدٌ
Open ayah 85:12Dájúdájú ìgbámú ti Olúwa rẹ mà le.
إِنَّهُۥ هُوَ يُبۡدِئُ وَيُعِيدُ
Open ayah 85:13Dájúdájú Òun ni Ó pìlẹ̀ (ẹ̀dá), Ó sì máa dá (ẹ̀dá) padà (fún àjíǹde).
وَهُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلۡوَدُودُ
Open ayah 85:14Òun ni Aláforíjìn, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá),
ذُو ٱلۡعَرۡشِ ٱلۡمَجِيدُ
Open ayah 85:15Òun l’Ó ni Ìtẹ́-ọlá, Ológo (Ẹni-ọ̀wọ̀ jùlọ),
فَعَّالٞ لِّمَا يُرِيدُ
Open ayah 85:16Olùṣe-ohun-t’Ó-bá-fẹ́.
هَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ ٱلۡجُنُودِ
Open ayah 85:17Ṣebí ìró àwọn ọmọ ogun ti dé ọ̀dọ̀ rẹ,
فِرۡعَوۡنَ وَثَمُودَ
Open ayah 85:18(ọmọ ogun) Fir‘aon àti (ìjọ) Thamūd?
بَلِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فِي تَكۡذِيبٖ
Open ayah 85:19Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì ń pe òdodo ní irọ́.
وَٱللَّهُ مِن وَرَآئِهِم مُّحِيطُۢ
Open ayah 85:20Allāhu sì yí wọn ká lẹ́yìn wọn.
بَلۡ هُوَ قُرۡءَانٞ مَّجِيدٞ
Open ayah 85:21Àmọ́ sá, ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ni) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé,
فِي لَوۡحٖ مَّحۡفُوظِۭ
Open ayah 85:22tí ó wà nínú wàláà tí wọ́n ń ṣọ́.