الطارق
At-Taariq
Translation: Yoruba - Abu Rahima Mikhail Aikweiny · Open the surah
بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
وَٱلسَّمَآءِ وَٱلطَّارِقِ
Open ayah 86:1(Allāhu) fi sánmọ̀ àti Tọ̄riƙ búra.
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلطَّارِقُ
Open ayah 86:2Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Tọ̄riƙ?
ٱلنَّجۡمُ ٱلثَّاقِبُ
Open ayah 86:3Ìràwọ̀ tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn ròrò (ní alẹ́ ni).
إِن كُلُّ نَفۡسٖ لَّمَّا عَلَيۡهَا حَافِظٞ
Open ayah 86:4Kò sí ẹ̀mí kan àfi kí ẹ̀ṣọ́ kan wà fún un (nínú àwọn mọlāika).
فَلۡيَنظُرِ ٱلۡإِنسَٰنُ مِمَّ خُلِقَ
Open ayah 86:5Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí ohun tí A fi ṣẹ̀dá rẹ̀.
خُلِقَ مِن مَّآءٖ دَافِقٖ
Open ayah 86:6Wọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú omi tó ń tú jáde kọ̀ọ́kọ̀ọ́.
يَخۡرُجُ مِنۢ بَيۡنِ ٱلصُّلۡبِ وَٱلتَّرَآئِبِ
Open ayah 86:7Ó ń jáde láti ààrin ìbàdí ọkùnrin àti àwọn ẹfọ́nhà igbá-àyà obìnrin.
إِنَّهُۥ عَلَىٰ رَجۡعِهِۦ لَقَادِرٞ
Open ayah 86:8Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lóri ìdápadà rẹ̀
يَوۡمَ تُبۡلَى ٱلسَّرَآئِرُ
Open ayah 86:9ní ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò àwọn (iṣẹ́) àṣepamọ́.
فَمَا لَهُۥ مِن قُوَّةٖ وَلَا نَاصِرٖ
Open ayah 86:10Nígbà náà, kò níí sí agbára tàbí alárànṣe kan fún un.
وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلرَّجۡعِ
Open ayah 86:11Allāhu fi sánmọ̀ tó ń rọ òjò ní ọdọọdún búra.
وَٱلۡأَرۡضِ ذَاتِ ٱلصَّدۡعِ
Open ayah 86:12Ó tún fi ilẹ̀ tó ń sán kànkàn (fún híhùjáde èso) búra.
إِنَّهُۥ لَقَوۡلٞ فَصۡلٞ
Open ayah 86:13Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀-ìpínyà (láààrin òdodo àti irọ́).
وَمَا هُوَ بِٱلۡهَزۡلِ
Open ayah 86:14Kì í sì ṣe àwàdà.
إِنَّهُمۡ يَكِيدُونَ كَيۡدٗا
Open ayah 86:15Dájúdájú wọ́n ń déte gan-an.
وَأَكِيدُ كَيۡدٗا
Open ayah 86:16Èmi náà sì ń déte gan-an.[1]
- Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.
فَمَهِّلِ ٱلۡكَٰفِرِينَ أَمۡهِلۡهُمۡ رُوَيۡدَۢا
Open ayah 86:17Nítorí náà, lọ́ra fún àwọn aláìgbàgbọ́. Lọ́ wọn lára sẹ́ fún ìgbà díẹ̀.