الأعلى
Al-A'laa
Translation: Yoruba - Abu Rahima Mikhail Aikweiny · Open the surah
بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
سَبِّحِ ٱسۡمَ رَبِّكَ ٱلۡأَعۡلَى
Open ayah 87:1Ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni gíga jùlọ.
ٱلَّذِي خَلَقَ فَسَوَّىٰ
Open ayah 87:2Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá. Ó sì ṣe (oríkèé-ríkèé rẹ̀) ní dọ́gbadọ́gba.
وَٱلَّذِي قَدَّرَ فَهَدَىٰ
Open ayah 87:3Ẹni tí Ó yan kádàrá (fún ẹ̀dá). Ó sì tọ́ ọ sọ́nà.[1]
- Nínú āyah yìí, mẹ́ta gbòòrò ni ìtọ́sọ́nà náà èyí tí Allāhu Afinimọ̀nà ń ṣe fún àwa ènìyàn àti àlùjànnú. Ìkíní: ìtọ́sọ́nà ẹ̀sìn ’Islām. Nítorí ìtọ́sọ́nà yìí gan-an ni Allāhu ṣe sọ àwọn Tírà Rẹ̀ kalẹ̀, tí Ó sì gbé àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ dìde sí wa. Ìkejì: ìtọ́sọ́nà ẹ̀rí-ọkàn. Nípa èyí ni a fi mọ ohun rere àti ohun burúkú ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìfirinlẹ̀ rẹ̀ sì ń jẹyọ nínú àwọn tírà sánmọ̀ àti nínú ọ̀rọ̀ àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -. Ìkẹta: ìtọ́sọ́nà òye àtinúwá. Nípa èyí ni a ṣe ń ṣàmúlò àwọn ohun àmúṣọrọ̀ fún ìgbáyé-gbádùn. Ìtọ́sọ́nà yìí kò sì sọ ẹnikẹ́ni di Òjíṣẹ́ Allāhu. Tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá rí ìtọ́sọ́nà ẹ̀sìn ’Islām nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀, kò sí ẹ̀san rere kan fún un lórí rẹ̀ ní ọ̀run. Ó kàn wúlò dànù fún ayé ni.
وَٱلَّذِيٓ أَخۡرَجَ ٱلۡمَرۡعَىٰ
Open ayah 87:4Ẹni tí Ó mú koríko tútù hù jáde,
فَجَعَلَهُۥ غُثَآءً أَحۡوَىٰ
Open ayah 87:5Ó sì sọ ọ́ di gbígbẹ tó dúdú.
سَنُقۡرِئُكَ فَلَا تَنسَىٰٓ
Open ayah 87:6Àwa yóò máa ké (al-Ƙur’ān) fún ọ. Ìwọ kò sì níí gbàgbé.
إِلَّا مَا شَآءَ ٱللَّهُۚ إِنَّهُۥ يَعۡلَمُ ٱلۡجَهۡرَ وَمَا يَخۡفَىٰ
Open ayah 87:7Àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́.[1] Dájúdájú Ó mọ gban̄gba àti ohun tó pamọ́.
- Ìyẹn nípasẹ̀ fífí ìdájọ́ kan pa ìdájọ́ tó ṣíwájú rẹ̀ rẹ́. Ẹ wo sūrah al-Baƙọrah; 2:106.
وَنُيَسِّرُكَ لِلۡيُسۡرَىٰ
Open ayah 87:8Àwa yó sì ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún ọ.
فَذَكِّرۡ إِن نَّفَعَتِ ٱلذِّكۡرَىٰ
Open ayah 87:9Nítorí náà, ṣèrántí ní àyè tí ìrántí ti wúlò.[1]
- Ìyẹn ni pé, wọ́n fẹ́ kí ṣíṣe ìrántí ọ̀rọ̀ Allāhu jìnnà sí àyè ìhunrírà (bí ilé ọtí), ilé eré àti ilé awàdà nítorí pé, àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀ kò níí kọbi ara sí olùsọ̀rọ̀. Āyah yìí jọ sūrah an-Nisā’; 4:140 àti sūrah al-’Ani‘ām; 6:68.
سَيَذَّكَّرُ مَن يَخۡشَىٰ
Open ayah 87:10Ẹni tí ó máa páyà (Allāhu) máa lo ìrántí.
وَيَتَجَنَّبُهَا ٱلۡأَشۡقَى
Open ayah 87:11Olórí-burúkú sì máa takété sí i.
ٱلَّذِي يَصۡلَى ٱلنَّارَ ٱلۡكُبۡرَىٰ
Open ayah 87:12(Òun sì ni) ẹni tí ó máa wọ inú Iná tó tóbi.
ثُمَّ لَا يَمُوتُ فِيهَا وَلَا يَحۡيَىٰ
Open ayah 87:13Lẹ́yìn náà, kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí ṣẹ̀mí (àlàáfíà).
قَدۡ أَفۡلَحَ مَن تَزَكَّىٰ
Open ayah 87:14Dájúdájú ẹni tí ó bá ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀sìn rẹ̀) ti jèrè.[1]
- Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mu’minūn; 23:4.
وَذَكَرَ ٱسۡمَ رَبِّهِۦ فَصَلَّىٰ
Open ayah 87:15Ó sì rántí orúkọ Olúwa rẹ̀, ó sì kírun.
بَلۡ تُؤۡثِرُونَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا
Open ayah 87:16Rárá, ńṣe l’ẹ̀ ń gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé.
وَٱلۡأٓخِرَةُ خَيۡرٞ وَأَبۡقَىٰٓ
Open ayah 87:17Ọ̀run sì lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé.
إِنَّ هَٰذَا لَفِي ٱلصُّحُفِ ٱلۡأُولَىٰ
Open ayah 87:18Dájúdájú èyí wà nínú àwọn tákàǹdá àkọ́kọ́,
صُحُفِ إِبۡرَٰهِيمَ وَمُوسَىٰ
Open ayah 87:19tákàdá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) Mūsā.