البلد

Al-Balad

The City · Surah 90 · Ayahs: 20 · Meccan

Translation: Yoruba - Abu Rahima Mikhail Aikweiny · Open the surah

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

  1. لَآ أُقۡسِمُ بِهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ

    Open ayah 90:1

    Èmi (Allāhu) ń fi ìlú yìí[1] búra.

    1. Ìbúra Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - àti ìbúra ẹ̀dá: Nígbà tí ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe kan bá jẹ́ kìkìdá òdodo àti àmọ̀dájú, ìbura lórí rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì tí a lè gba ṣe àfihàn ìdánilójú rẹ̀ fún ẹlòmíìràn nítorí kí ó lè bi iyèméjì àti rújúrújú wó lulẹ̀ nínú ọkàn rẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ àti ìṣe Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sì ti dájú pé iṣẹ́ Ọwọ́ Rẹ̀ ni níti òdodo àti àmọ̀dàjù, ẹ̀tọ́ ni fún Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - láti fi èyíkéyìí nínú wọn búra. Ṣebí iṣẹ́ ọwọ́ Allāhu ni gbogbo bíbẹ. Àmọ́, ẹ̀dá kan kò gbọdọ̀ fi ẹ̀dá mìíràn búra nítorí pé, ẹ̀dá kan kì í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ ẹ̀dá mìíràn. Allāhu nìkan ni òdodo àti àmọ̀dájú fún ẹ̀dá pé, Òun nìkan ni Ẹlẹ́dàá wa tí a lè fi búra nítorí pé, fífi Allāhu nìkan ṣoṣo búra ni ẹ̀sìn gbà wá láyè mọ láti fi búra. Bíbá Allāhu wá akẹgbẹ́ (ẹbọ ṣíṣe) sì ni fífi n̄ǹkan mìíràn búra lẹ́yìn Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -.
  2. وَأَنتَ حِلُّۢ بِهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ

    Open ayah 90:2

    Ìwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀).[1]

    1. Ẹ̀tọ́ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fún Ànábì Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni kíkógun ja ìlú Mọkkah lásìkò ogun Ìṣí Mọkkah “Fat-hu Mọkkah”. Ṣíwájú àsìkò yìí àti lẹ́yìn rẹ̀, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ẹnikẹ́ni mọ́ láti jagun nínú ìlú Mọkkah alápọ̀n-ọ́nlé.
  3. وَوَالِدٖ وَمَا وَلَدَ

    Open ayah 90:3

    Èmi (Allāhu) ń fi òbí àti ohun tó bí búra.

  4. لَقَدۡ خَلَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ فِي كَبَدٍ

    Open ayah 90:4

    Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro.

  5. أَيَحۡسَبُ أَن لَّن يَقۡدِرَ عَلَيۡهِ أَحَدٞ

    Open ayah 90:5

    Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni?

  6. يَقُولُ أَهۡلَكۡتُ مَالٗا لُّبَدًا

    Open ayah 90:6

    Ó (sì) ń wí pé: “Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -)”

  7. أَيَحۡسَبُ أَن لَّمۡ يَرَهُۥٓ أَحَدٌ

    Open ayah 90:7

    Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni?

  8. أَلَمۡ نَجۡعَل لَّهُۥ عَيۡنَيۡنِ

    Open ayah 90:8

    Ṣé A kò ṣe ojú méjì fún un?

  9. وَلِسَانٗا وَشَفَتَيۡنِ

    Open ayah 90:9

    Àti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un)?

  10. وَهَدَيۡنَٰهُ ٱلنَّجۡدَيۡنِ 

    Open ayah 90:10

    A sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n.

  11. فَلَا ٱقۡتَحَمَ ٱلۡعَقَبَةَ

    Open ayah 90:11

    Kò sì lọ rin ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí níbi Iná!

  12. وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡعَقَبَةُ

    Open ayah 90:12

    Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí?

  13. فَكُّ رَقَبَةٍ

    Open ayah 90:13

    (Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú.

  14. أَوۡ إِطۡعَٰمٞ فِي يَوۡمٖ ذِي مَسۡغَبَةٖ

    Open ayah 90:14

    Tàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi.

  15. يَتِيمٗا ذَا مَقۡرَبَةٍ

    Open ayah 90:15

    (Ẹ lè fún) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí,

  16. أَوۡ مِسۡكِينٗا ذَا مَتۡرَبَةٖ

    Open ayah 90:16

    tàbí mẹ̀kúnnù tí kò ní gá tí kò ní go (olòṣì paraku).

  17. ثُمَّ كَانَ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلصَّبۡرِ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلۡمَرۡحَمَةِ

    Open ayah 90:17

    Lẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe.

  18. أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَيۡمَنَةِ

    Open ayah 90:18

    Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún.

  19. وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِنَا هُمۡ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَشۡـَٔمَةِ

    Open ayah 90:19

    Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, àwọn ni èrò ọwọ́ òsì.[1]

    1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Wāƙi‘ah; 56:7.
  20. عَلَيۡهِمۡ نَارٞ مُّؤۡصَدَةُۢ 

    Open ayah 90:20

    Wọ́n máa ti àwọn ìlẹ̀kùn Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.