الهمزة
Al-Humaza
Translation: Yoruba - Abu Rahima Mikhail Aikweiny · Open the surah
بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
وَيۡلٞ لِّكُلِّ هُمَزَةٖ لُّمَزَةٍ
Open ayah 104:1Ègbé ni fún gbogbo abúnilójú-ẹni, abúnilẹ́yìn-ẹni,
ٱلَّذِي جَمَعَ مَالٗا وَعَدَّدَهُۥ
Open ayah 104:2ẹni tí ó kó dúkìá jọ, tí ó sì kà á lákàtúnkà (láì ná an fún ẹ̀sìn).
يَحۡسَبُ أَنَّ مَالَهُۥٓ أَخۡلَدَهُۥ
Open ayah 104:3Ó ń lérò pé dájúdájú dúkìá rẹ̀ yóò mú un ṣe gbére (nílé ayé).
كَلَّاۖ لَيُنۢبَذَنَّ فِي ٱلۡحُطَمَةِ
Open ayah 104:4Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀). Dájúdájú wọ́n máa kù ú lókò sínú Hutọmọh ni.
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡحُطَمَةُ
Open ayah 104:5Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Hutọmọh?
نَارُ ٱللَّهِ ٱلۡمُوقَدَةُ
Open ayah 104:6(Òhun ni) Iná Allāhu tí wọ́n ń kò (tó ń jó geregere),
ٱلَّتِي تَطَّلِعُ عَلَى ٱلۡأَفۡـِٔدَةِ
Open ayah 104:7èyí tí ó máa jó (ẹ̀dá) wọ inú ọkàn lọ.
إِنَّهَا عَلَيۡهِم مُّؤۡصَدَةٞ
Open ayah 104:8Dájúdájú wọ́n máa ti (àwọn ìlẹ̀kùn) Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.
فِي عَمَدٖ مُّمَدَّدَةِۭ
Open ayah 104:9(Wọ́n máa wà) láààrin àwọn òpó kìrìbìtì gíga (nínú Iná).