الفاتحة

Al-Faatiha

The Opening · Surah 1 · Ayahs: 7 · Meccan

Translation: Yoruba - Abu Rahima Mikhail Aikweiny · Open the surah

  1. بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

    Open ayah 1:1

    Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.[1]

    1. Sūratun Mọkkiyyah túmọ̀ sí sūrah tí ó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú Hijrah. Bákan náà, sūratun Mọdaniyyah túmọ̀ sí sūrah tí ó sọ̀kalẹ̀ lẹ́yìn Hijrah. Ìyẹn ni pé, Hijrah tí àwọn mùsùlùmí ṣe láti ìlú Mọkkah Alápọ̀n-ọ́nlé sí ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀ ni wọ́n fi pín gbogbo sūrah al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé sábẹ́ sūratun Mọkkiyyah àti sūratun Mọdaniyyah. Ìwọ̀nyí ni àwọn orúkọ sūrah yìí: (1) Fātihatul-kitāb “Sūrah Ìbẹ̀rẹ̀ Tírà (ìyẹn ní ti àkọsílẹ̀, kì í ṣe ní ti ìsọ̀kalẹ̀.” (2) ’Ummul-Ƙur’ān “Ìpìlẹ̀ al-Ƙur’ān”, (3) ’Ummul-kitāb “Ìpìlẹ̀ Tírà”, (4) as-Sab‘u al-mọthāniy “sūrah alāyah méje tí ó kún fún ẹyìn Allāhu” (Wọ́n ṣí “bismillāh ar-rahmọ̄n ar-rọhīm” mọ́ ọn.)“, (5) al-Ƙur’ān al-‘aṭḥīm “N̄ǹkan Kíkà ńlá”, (6) al-hamd “ẹyìn”, (7) as-sọlāt “ìrun”, (8) aṣ-ṣifā’ “ìwòsàn” àti (9) ar-ruƙyah “àdúà pàjáwìrì”.
  2. ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

    Open ayah 1:2

    Gbogbo ẹyìn[1] ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa[2] gbogbo ẹ̀dá,

  3. ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

    Open ayah 1:3

    Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run,

  4. مَٰلِكِ يَوۡمِ ٱلدِّينِ

    Open ayah 1:4

    Olùkápá-ọjọ́-ẹ̀san.

  5. إِيَّاكَ نَعۡبُدُ وَإِيَّاكَ نَسۡتَعِينُ

    Open ayah 1:5

    Ìwọ nìkan ni à ń jọ́sìn fún. Ọ̀dọ̀ Rẹ nìkan sì ni à ń wá oore sí.[1]

    1. Èyí ni àdéhùn ojoojúmọ́ tí à ń ṣe fún Allāhu, Ọlọ́hun tí a gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Nítorí náà, èèwọ̀ ẹ̀sìn ni fún mùsùlùmí láti yapa àdéhùn náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa àdéhùn náà, ó ti di ẹlẹ́bọ pọ́nńbélé títí ó fi máa ronú pìwàdà.
  6. ٱهۡدِنَا ٱلصِّرَٰطَ ٱلۡمُسۡتَقِيمَ

    Open ayah 1:6

    Fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ l’ójú ọ̀nà tààrà (’Islām),[1]

    1. Sirọ̄tun mustaƙīm “ọ̀nà tààrà” jẹyọ ní àyè 33 nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Ó sì dúró fún ìwọ̀nyí: (1) Jíjìnnà sí ẹbọ ṣíṣe, jíjìnnà sí ìwà ìbàjẹ́, ṣíṣe rere àti lílo òfin Allāhu; ìtúmọ̀ yìí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-’Ani-‘Ām; 6:151-153. (2) Jíjọ́sìn fún Allāhu níkan ṣoṣo àti dídúró ṣinṣin nínú ìjọ́sìn Rẹ̀; ìtúmọ̀ yìí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah Āli ‘Imrọ̄n; 3:51&101 (3) Ẹ̀sìn kan ṣoṣo tí gbogbo àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu ṣe; ìtúmọ̀ yìí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-’Ani-‘Ām; 6:83-90. (4) Ẹ̀sìn ’Islām; ìtúmọ̀ yìí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-’Ani-‘Ām; 6:125-126. Nítorí náà, kò sí àyè kan nínú al-Ƙur’ān tí ọ̀nà tààrà ti dúró fún ẹ̀sìn nasọ̄rọ̄ tàbí ẹ̀sìn yẹhudi. Nígbà tí mùsùlùmí bá sì ń ṣàdúà ní gbogbo ìgbà pé “ihdina-ssirọ̄tọl-mustaƙīm” ìtúmọ̀ rẹ̀ ni pé, “Fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ l’ójú ọ̀nà tààrà.” Ìyẹn ni pé, “Fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ sínú ’Islām ọ̀nà tààrà.” Nítorí náà, àdúà ìfẹsẹ̀rinlẹ̀ sínú ẹ̀sìn ’Islām títí d’ọjọ́ ikú ni àdúà náà dúró fún. Àti pé, āyah 7 ti yanjú ọ̀rọ̀ náà pé, kì í ṣe ọ̀nà yẹhudi nítorí pé, wọ́n ti di ẹni ìbínú lọ́dọ̀ Allāhu. Kì í sì ṣe ọ̀nà nasọ̄rọ̄ nítorí pé, wọ́n ti di olùṣìnà. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7:23. = Kíyè sí i! Ìdí tí àdúà yìí sì fi pàtàkì púpọ̀ ni pé, tí ènìyàn bá ṣe ẹ̀sìn ’Islām, kò lè jèrè rẹ̀ àyàfi kí ó kú sínú rẹ̀ nítorí sūrah Āli-‘Imrọ̄n; 3:102 Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Ƙọsọs; 28:56.
  7. صِرَٰطَ ٱلَّذِينَ أَنۡعَمۡتَ عَلَيۡهِمۡ غَيۡرِ ٱلۡمَغۡضُوبِ عَلَيۡهِمۡ وَلَا ٱلضَّآلِّينَ

    Open ayah 1:7

    ọ̀nà àwọn tí O ṣe ìdẹ̀ra fún,[1] yàtọ̀ sí (ọ̀nà) àwọn ẹni-ìbínú (ìyẹn, àwọn yẹhudi) àti (ọ̀nà) àwọn olùṣìnà (ìyẹn, àwọn nasọ̄rọ̄).

    1. Àwọn wo gan-an ni àwọn tí Allāhu ṣe ìdẹ̀ra fún, tí àwa mùsùlùmí ń tọ ojú-ọ̀nà wọn? Ẹ ka sūrah Mọryam;19:58.